Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 11:9-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Oluwa si wi fun mi pe, A ri ìditẹ lãrin awọn ọkunrin Juda ati lãrin awọn olugbe Jerusalemu.

10. Nwọn yipada si ẹ̀ṣẹ iṣaju awọn baba wọn ti o kọ̀ lati gbọ́ ọ̀rọ mi; awọn wọnyi si tọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati sìn wọn: ile Israeli ati ile Juda ti dà majẹmu mi ti mo ba awọn baba wọn dá.

11. Nitorina, bayi li Oluwa wi, sa wò o, Emi o mu ibi wá sori wọn, ti nwọn kì yio le yẹba fun: bi nwọn tilẹ ke pè mi, emi kì yio fetisi igbe wọn.

12. Jẹ ki ilu Juda ati awọn olugbe Jerusalemu ki o lọ, ki nwọn ki o si ke pe awọn ọlọrun ti nwọn ńsun turari fun, ṣugbọn lõtọ nwọn kì yio le gba wọn ni igba ipọnju wọn.

13. Nitori bi iye ilu rẹ, bẹ̃ni iye ọlọrun rẹ, iwọ Juda, ati bi iye ita Jerusalemu, bẹ̃ni iye pẹpẹ ti ẹnyin ti tẹ́ fun ohun itìju nì, pẹpẹ lati sun turari fun Baali.

14. Nitorina máṣe gbadura fun awọn enia yi, bẹ̃ni ki o má si ṣe gbe ohùn ẹkun tabi ti adura soke fun wọn, nitori emi kì yio gbọ́ ni igba ti nwọn ba kigbe pè mi, ni wakati wahala wọn.

15. Kini olufẹ mi ni iṣe ni ile mi? nigbati nwọn nṣe buburu pupọ bayi? adura on ẹran mimọ́ ha le mu ibi kọja kuro lọdọ rẹ? bi o ba ri bayi? nigbana jẹ ki inu rẹ ki o dùn.

16. Oluwa pè orukọ rẹ ni igi Olifi tutu, didara, eleso rere: ṣugbọn nisisiyi o fi ariwo irọkẹkẹ nla dá iná lara rẹ̀, ẹka rẹ̀ li o si faya.

17. Nitori Oluwa awọn ọmọ-ogun, ti o gbìn ọ, ti sọ̀rọ ibi si ọ, nitori buburu ile Israeli, ati ile Juda, ti nwọn ti ṣe si ara wọn lati ru ibinu mi soke ni sisun turari fun Baali.

18. Oluwa si ti mu mi mọ̀, emi si mọ̀: nigbana ni iwọ fi iṣe wọn hàn mi.

19. Ani mo dabi ọdọ-agutan ti o mọ̀ oju ile, ti a mu wá fun pipa: emi kò si mọ̀ pe, nwọn ti pinnu buburu si mi wipe: Jẹ ki a ke igi na pẹlu eso rẹ̀ ki a si ke e kuro ni ilẹ alãye, ki a máṣe ranti orukọ rẹ̀ mọ.

Ka pipe ipin Jer 11