Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 11:17-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Nitori Oluwa awọn ọmọ-ogun, ti o gbìn ọ, ti sọ̀rọ ibi si ọ, nitori buburu ile Israeli, ati ile Juda, ti nwọn ti ṣe si ara wọn lati ru ibinu mi soke ni sisun turari fun Baali.

18. Oluwa si ti mu mi mọ̀, emi si mọ̀: nigbana ni iwọ fi iṣe wọn hàn mi.

19. Ani mo dabi ọdọ-agutan ti o mọ̀ oju ile, ti a mu wá fun pipa: emi kò si mọ̀ pe, nwọn ti pinnu buburu si mi wipe: Jẹ ki a ke igi na pẹlu eso rẹ̀ ki a si ke e kuro ni ilẹ alãye, ki a máṣe ranti orukọ rẹ̀ mọ.

20. Ṣugbọn Oluwa awọn ọmọ-ogun, onidajọ otitọ ti ndan aiya ati inu wò, emi o ri igbẹsan rẹ lori wọn: nitori iwọ ni mo fi ọ̀ran mi le lọwọ.

21. Nitorina bayi li Oluwa wi, niti enia Anatoti ti o nwá ẹmi rẹ, ti nwipe, Máṣe sọ asọtẹlẹ li orukọ Oluwa, ki iwọ ki o má ba kú nipa, ọwọ wa.

22. Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, wò o, emi o bẹ̀ wọn wo, awọn ọdọmọkunrin o ti ọwọ idà kú, ọmọ wọn ọkunrin ati ọmọ wọn obinrin yio kú nipa iyàn:

23. Ẹnikan kì yio kù ninu wọn: nitori emi o mu ibi wá sori awọn enia Anatoti, ani ọdun ìbẹwo wọn.

Ka pipe ipin Jer 11