Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 10:19-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Egbe ni fun mi nitori ipalara mi! ọgbẹ mi pọ̀: ṣugbọn mo wipe, nitõtọ ìya mi ni eyi, emi o si rù u.

20. Agọ mi bajẹ, gbogbo okùn mi si ja: awọn ọmọ mi ti fi mi silẹ lọ, nwọn kò sí mọ́, kò si ẹnikan ti yio nà agọ mi mọ, ti yio si ta aṣọ ikele mi.

21. Nitori awọn oluṣọ agutan ti di ope, nwọn kò si wá Oluwa: nitorina nwọn kì yio ri rere, gbogbo agbo wọn yio si tuka.

22. Sa wò o, ariwo igbe ti de, ati irukerudo nla lati ilẹ ariwa wá, lati sọ ilu Judah di ahoro, ati iho ọwawa.

23. Oluwa! emi mọ̀ pe, ọ̀na enia kò si ni ipa ara rẹ̀: kò si ni ipá enia ti nrin, lati tọ́ iṣisẹ rẹ̀.

24. Oluwa kilọ fun mi, ṣugbon ni idajọ ni, ki o máṣe ni ibinu rẹ, ki iwọ ki o má sọ mi di asan.

25. Tu ibinu rẹ si ori awọn orilẹ-ède, ti kò mọ̀ ọ, ati sori awọn idile ti kò ke pè orukọ rẹ, nitoriti nwọn ti jẹ Jakobu run, nwọn si gbe e mì, nwọn si pa a run tan, nwọn si sọ ibugbe rẹ̀ di ahoro.

Ka pipe ipin Jer 10