Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 65:1-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. A wá mi lọdọ awọn ti kò bere mi; a ri mi lọdọ awọn ti kò wá mi: mo wi fun orilẹ-ède ti a kò pe li orukọ mi pe, Wò mi, wò mi.

2. Ni gbogbo ọjọ ni mo ti na ọwọ́ mi si awọn ọlọtẹ̀ enia, ti nrìn li ọ̀na ti kò dara, nipa ìro ara wọn;

3. Awọn enia ti o nṣọ́ mi ni inu nigbagbogbo kàn mi loju; ti nrubọ ninu agbàla, ti nwọn si nfi turari jona lori pẹpẹ briki.

4. Awọn ti ngbe inu ibojì, ti nwọn si nwọ̀ ni ile awọn oriṣa, ti njẹ ẹran ẹlẹdẹ, omi-ẹran nkan irira si mbẹ ninu ohun-elò wọn;

5. Ẹniti o wipe, Duro fun ara rẹ, máṣe sunmọ mi; nitori ti mo ṣe mimọ́ jù ọ lọ. Wọnyi li ẹ̃fin ni imu mi, iná ti njo ni gbogbo ọjọ ni.

6. Kiyesi i, a ti kọwe rẹ̀ niwaju mi: emi kì o dakẹ, ṣugbọn emi o gbẹ̀san, ani ẹ̀san si aiya wọn,

7. Aiṣedede nyin, ati aiṣedede awọn baba nyin ṣọkan pọ̀, li Oluwa wi, awọn ẹniti o fi turari jona lori oke-nla, ti nwọn mbu ọla mi kù lori awọn oke kékèké: nitori na li emi o wọ̀n iṣẹ wọn iṣaju, sinu aiya wọn.

8. Bayi ni Oluwa wi, gẹgẹ bi a ti iri ọti-waini titun ninu ìdi eso àjara, ti a si nwipe, Máṣe bà a jẹ nitori ibukun mbẹ ninu rẹ̀: bẹ̃li emi o ṣe nitori awọn iranṣẹ mi, ki emi ki o má ba pa gbogbo wọn run.

9. Emi o si mu iru kan jade ni Jakobu, ati ajogun oke-nla mi lati inu Juda: ayanfẹ mi yio si jogun rẹ̀, awọn iranṣẹ mi yio si gbe ibẹ.

10. Ṣaroni yio di agbo-ẹran, ati afonifoji Akori ibikan fun awọn ọwọ́ ẹran lati dubulẹ ninu rẹ̀, nitori awọn enia mi ti o ti wá mi kiri.

11. Ṣugbọn ẹnyin ti o kọ̀ Oluwa silẹ, ti o gbàgbe oke-nla mimọ́ mi, ti o pèse tabili fun Gadi, ti o si fi ọrẹ mimu kun Meni.

12. Nitorina li emi o ṣe kà nyin fun idà, gbogbo nyin yio wolẹ fun pipa: nitori nigbati mo pè, ẹnyin kò dahùn; nigbati mo sọ̀rọ, ẹnyin kò gbọ́; ṣugbọn ẹnyin ṣe ibi loju mi, ẹnyin si yàn eyiti inu mi kò dùn si.

13. Nitorina bayi ni Oluwa Jehofah wi, Kiyesi i awọn iranṣẹ mi o jẹun, ṣugbọn ebi yio pa ẹnyin: kiyesi i, awọn iranṣẹ mi o mu, ṣugbọn ongbẹ o gbẹ ẹnyin: kiyesi i, awọn iranṣẹ mi o yọ̀, ṣugbọn oju o tì ẹnyin:

14. Kiyesi i, awọn iranṣẹ mi yio kọrin fun inudidun, ṣugbọn ẹnyin o ke fun ibanujẹ ọkàn, ẹnyin o si hu fun irobinujẹ ọkàn.

15. Ẹnyin o si fi orukọ nyin silẹ fun egún fun awọn ayanfẹ mi: nitori Oluwa Jehofah yio pa ọ, yio si pè awọn iranṣẹ rẹ̀ li orukọ miran:

16. Ki ẹniti o fi ibukun fun ara rẹ̀ li aiye, ki o fi ibukun fun ara rẹ̀ ninu Ọlọrun otitọ; ẹniti o si mbura li aiye ki o fi Ọlọrun otitọ bura; nitori ti a gbagbe wahala iṣaju, ati nitoriti a fi wọn pamọ kuro loju mi.

17. Sa wò o, emi o da ọrun titun ati aiye titun: a kì yio si ranti awọn ti iṣaju, bẹ̃ni nwọn kì yio wá si aiya.

Ka pipe ipin Isa 65