Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 63:2-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Nitori kini aṣọ rẹ fi pọ́n, ti aṣọ rẹ wọnni fi dabi ẹniti ntẹ̀ ohun-èlo ifunti waini?

3. Emi nikan ti tẹ̀ ohun-elò ifunti waini; ati ninu awọn enia, ẹnikan kò pẹlu mi: nitori emi tẹ̀ wọn ninu ibinu mi, mo si tẹ̀ wọn mọlẹ ninu irunú mi; ẹ̀jẹ wọn si ta si aṣọ mi, mo si ṣe gbogbo ẹ̀wu mi ni abawọ́n.

4. Nitori ọjọ ẹsan mbẹ li aiya mi, ọdun awọn ẹni-irapada mi ti de.

5. Mo si wò, kò si si oluranlọwọ; ẹnu si yà mi pe kò si olugbéro; nitorina apa ti emi tikalami mu igbala wá sọdọ mi; ati irunú mi, on li o gbe mi ro.

6. Emi si tẹ̀ awọn enia mọlẹ ninu ibinu mi, mo si mu wọn mu yó ninu irunú mi, mo si mu ipa wọn sọkalẹ si ilẹ.

7. Emi o sọ ti iṣeun ifẹ Oluwa, iyìn Oluwa gẹgẹ bi gbogbo eyiti Oluwa ti fi fun wa, ati ti ore nla si ile Israeli, ti o ti fi fun wọn gẹgẹ bi ãnu rẹ̀, ati gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ iṣeun ifẹ rẹ̀.

8. On si wipe, Lõtọ enia mi ni nwọn, awọn ọmọ ti kì iṣeke: on si di Olugbala wọn.

9. Ninu gbogbo ipọnju wọn, oju a pọn ọ, angeli iwaju rẹ̀ si gbà wọn: ninu ifẹ rẹ̀ ati suru rẹ̀ li o rà wọn pada; o si gbe wọn, o si rù wọn ni gbogbo ọjọ igbani.

10. Ṣugbọn nwọn ṣọ̀tẹ, nwọn si bi Ẹmi mimọ́ rẹ̀ ninu; nitorina li o ṣe pada di ọta wọn, on tikalarẹ̀ si ba wọn ja.

11. Nigbana ni o ranti ọjọ atijọ, Mose, awọn enia rẹ̀, wipe, Nibo li ẹniti o mu wọn ti inu okun jade gbe wà, ti on ti olùṣọ agutan ọwọ́-ẹran rẹ̀? nibo li ẹniti o fi Ẹmi mimọ́ rẹ̀ sinu rẹ̀ gbe wà?

Ka pipe ipin Isa 63