Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 63:11-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Nigbana ni o ranti ọjọ atijọ, Mose, awọn enia rẹ̀, wipe, Nibo li ẹniti o mu wọn ti inu okun jade gbe wà, ti on ti olùṣọ agutan ọwọ́-ẹran rẹ̀? nibo li ẹniti o fi Ẹmi mimọ́ rẹ̀ sinu rẹ̀ gbe wà?

12. Ti o fi ọwọ́ ọtun Mose dà wọn, pẹlu apá rẹ̀ ti o logo, ti o npin omi meji niwaju wọn, lati ṣe orukọ aiyeraiye fun ara rẹ̀?

13. Ti o mu wọn là ibú ja, bi ẹṣin li aginjù, ki nwọn ki o má ba kọsẹ?

14. Gẹgẹ bi ẹran ti isọ̀kalẹ lọ si afonifoji, bẹ̃ni Ẹmi Oluwa mu u simi: bẹ̃ni iwọ tọ́ awọn enia rẹ, lati ṣe orukọ ti o li ogo fun ara rẹ.

15. Wò ilẹ lati ọrun wá, ki o si kiyesi lati ibugbe ìwa mimọ́ rẹ ati ogo rẹ wá: nibo ni itara rẹ ati agbara rẹ, ọ̀pọlọpọ iyanu rẹ, ati ãnu rẹ sọdọ mi gbe wà? a ha da wọn duro bi?

16. Laiṣiyemeji iwọ ni baba wa, bi Abrahamu tilẹ ṣe alaimọ̀ wa, ti Israeli kò si jẹwọ wa: iwọ Oluwa, ni baba wa, Olurapada wa; lati aiyeraiye ni orukọ rẹ.

17. Oluwa, nitori kili o ṣe mu wa ṣina kuro li ọ̀na rẹ, ti o si sọ ọkàn wa di lile kuro ninu ẹ̀ru rẹ? Yipada nitori awọn iranṣẹ rẹ, awọn ẹya ilẹ ini rẹ.

18. Awọn enia mimọ́ rẹ ti ni i, ni igba diẹ: awọn ọta wa ti tẹ̀ ibi mimọ́ rẹ mọlẹ.

19. Tirẹ li awa: lati lailai iwọ kò jọba lori wọn, a kò pè orukọ rẹ mọ wọn.

Ka pipe ipin Isa 63