Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 63:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. TANI eleyi ti o ti Edomu wá, ti on ti aṣọ arẹpọ́n lati Bosra wá? eyi ti o li ogo ninu aṣọ rẹ̀, ti o nyan ninu titobi agbara rẹ̀? Emi ni ẹniti nsọ̀rọ li ododo, ti o ni ipá lati gbala.

2. Nitori kini aṣọ rẹ fi pọ́n, ti aṣọ rẹ wọnni fi dabi ẹniti ntẹ̀ ohun-èlo ifunti waini?

3. Emi nikan ti tẹ̀ ohun-elò ifunti waini; ati ninu awọn enia, ẹnikan kò pẹlu mi: nitori emi tẹ̀ wọn ninu ibinu mi, mo si tẹ̀ wọn mọlẹ ninu irunú mi; ẹ̀jẹ wọn si ta si aṣọ mi, mo si ṣe gbogbo ẹ̀wu mi ni abawọ́n.

4. Nitori ọjọ ẹsan mbẹ li aiya mi, ọdun awọn ẹni-irapada mi ti de.

5. Mo si wò, kò si si oluranlọwọ; ẹnu si yà mi pe kò si olugbéro; nitorina apa ti emi tikalami mu igbala wá sọdọ mi; ati irunú mi, on li o gbe mi ro.

6. Emi si tẹ̀ awọn enia mọlẹ ninu ibinu mi, mo si mu wọn mu yó ninu irunú mi, mo si mu ipa wọn sọkalẹ si ilẹ.

7. Emi o sọ ti iṣeun ifẹ Oluwa, iyìn Oluwa gẹgẹ bi gbogbo eyiti Oluwa ti fi fun wa, ati ti ore nla si ile Israeli, ti o ti fi fun wọn gẹgẹ bi ãnu rẹ̀, ati gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ iṣeun ifẹ rẹ̀.

Ka pipe ipin Isa 63