Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 62:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NITORI ti Sioni emi kì yio dakẹ, ati nitori ti Jerusalemu emi kì yio simi, titi ododo rẹ̀ yio fi jade bi titan imọlẹ, ati igbala rẹ̀ bi fitila ti njó.

2. Ati awọn Keferi yio ri ododo rẹ, ati gbogbo ọba yio ri ogo rẹ: a o si fi orukọ titun pè ọ, eyiti ẹnu Oluwa yio darukọ.

3. Iwọ o jẹ ade ogo pẹlu li ọwọ́ Oluwa, ati adé oyè ọba li ọwọ́ Ọlọrun rẹ.

4. A ki yio pè ọ ni Ikọ̀silẹ mọ́, bẹ̃ni a ki yio pè ilẹ rẹ ni Ahoro mọ: ṣugbọn a o pè ọ ni Hefsiba: ati ilẹ rẹ ni Beula: nitori inu Oluwa dùn si ọ, a o si gbe ilẹ rẹ ni iyawo.

5. Gẹgẹ bi ọdọmọkunrin ti igbé wundia ni iyawo, bẹ̃ni awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio gbe ọ ni iyawo: ati bi ọkọ iyawo ti iyọ̀ si iyawo, bẹ̃ni Ọlọrun rẹ yio yọ̀ si ọ.

Ka pipe ipin Isa 62