Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 57:12-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Emi o fi ododo rẹ, ati iṣẹ rẹ hàn; nwọn kì o si gbè ọ.

13. Nigbati iwọ ba kigbe, jẹ ki awọn ẹgbẹ rẹ ki o gbà ọ; ṣugbọn ẹfũfu ni yio gbá gbogbo wọn lọ; emi yio mu wọn kuro: ṣugbọn ẹniti o ba gbẹkẹ rẹ̀ le mi yio ni ilẹ na, yio si jogun oke mimọ́ mi.

14. On o si wipe, Ẹ kọ bèbe, ẹ kọ bèbe, ẹ tun ọ̀na ṣe; ẹ mu ìdugbolu kuro li ọ̀na awọn enia mi.

15. Nitori bayi li Ẹni-giga, ati ẹniti a gbéga soke sọ, ti ngbe aiyeraiye, orukọ ẹniti ijẹ Mimọ́, emi ngbe ibi giga ati mimọ́, ati inu ẹniti o li ẹmi irobinujẹ on irẹlẹ pẹlu, lati mu ẹmi awọn onirẹlẹ sọji, ati lati mu ọkàn awọn oniròbinujẹ sọji.

16. Nitori emi kì yio jà titi lai, bẹ̃ni emi kì yio binu nigbagbogbo: nitori ẹmi iba daku niwaju mi, ati ẽmi ti emi ti dá.

17. Mo ti binu nitori aiṣedede ojukokoro rẹ̀, mo si lù u: mo fi oju pamọ́, mo si binu, on si nlọ ni iṣìna li ọ̀na ọkàn rẹ̀.

18. Mo ti ri ọ̀na rẹ̀, emi o si mu u li ara da: emi o si tọ́ ọ pẹlu, emi o si mu itunu pada fun u wá, ati fun awọn aṣọ̀fọ rẹ̀.

19. Emi li o da eso ète; Alafia, alafia fun ẹniti o jina rére, ati fun ẹniti o wà nitosí, ni Oluwa wi; emi o si mu u li ara da.

20. Ṣugbọn awọn enia buburu dabi okun ríru, nigbati kò le simi, eyiti omi rẹ̀ nsọ ẹrẹ ati ẽri soke.

21. Alafia kò si fun awọn enia buburu, ni Ọlọrun mi wi.

Ka pipe ipin Isa 57