Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 57:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLODODO ṣegbe, kò si ẹniti o kà a si: a mu awọn alãnu kuro, kò si ẹniti nrò pe a mu olododo kuro ṣaju ibi.

2. On wọ̀ inu alafia: nwọn simi lori akete wọn, olukuluku ẹniti nrin ninu iduroṣinṣin rẹ̀.

3. Ṣugbọn ẹ sunmọ ihin, ẹnyin ọmọ oṣo, iru-ọmọ panṣaga on àgbere.

4. Tani ẹnyin fi nṣe ẹsín? tani ẹnyin nyanu gborò si, ti ẹnyin yọ ahọn jade si? ọmọ alarekọja ki ẹnyin, iru-ọmọ eke,

5. Ti òriṣa ngùn labẹ gbogbo igi tutù, ti ẹ npa awọn ọmọ wẹrẹ ninu afonifoji wọnni, labẹ apáta ti o yanu?

6. Lãrin okuta ọ̀bọrọ́ odo ni ipín rẹ, awọn, awọn ni ipín rẹ: ani awọn ni iwọ dà ẹbọ ọrẹ mimu si: ti iwọ si rú ẹbọ ọrẹ jijẹ. Emi ha le gbà itunu ninu wọnyi?

7. Lori oke giga giga ni iwọ fi akete rẹ si, ani nibẹ ni iwọ ti lọ lati rú ẹbọ.

8. Lẹhin ilẹkùn ati opó ilẹkun ni iwọ si ti gbe iranti rẹ soke: nitori iwọ ti fi ara rẹ hàn fun ẹlomiran dipò mi, iwọ si ti goke: iwọ ti sọ akete rẹ di nla, iwọ si ba wọn dá majẹmu; iwọ ti fẹ akete wọn nibiti iwọ ri i.

9. Iwọ si ti lọ tiwọ ti ikunra sọdọ ọba, iwọ si ti sọ õrùn didùn rẹ di pupọ, iwọ si ti rán awọn ikọ̀ rẹ lọ jina réré, iwọ si ti rẹ̀ ara rẹ silẹ, ani si ipò okú.

Ka pipe ipin Isa 57