Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 57:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLODODO ṣegbe, kò si ẹniti o kà a si: a mu awọn alãnu kuro, kò si ẹniti nrò pe a mu olododo kuro ṣaju ibi.

2. On wọ̀ inu alafia: nwọn simi lori akete wọn, olukuluku ẹniti nrin ninu iduroṣinṣin rẹ̀.

3. Ṣugbọn ẹ sunmọ ihin, ẹnyin ọmọ oṣo, iru-ọmọ panṣaga on àgbere.

4. Tani ẹnyin fi nṣe ẹsín? tani ẹnyin nyanu gborò si, ti ẹnyin yọ ahọn jade si? ọmọ alarekọja ki ẹnyin, iru-ọmọ eke,

5. Ti òriṣa ngùn labẹ gbogbo igi tutù, ti ẹ npa awọn ọmọ wẹrẹ ninu afonifoji wọnni, labẹ apáta ti o yanu?

6. Lãrin okuta ọ̀bọrọ́ odo ni ipín rẹ, awọn, awọn ni ipín rẹ: ani awọn ni iwọ dà ẹbọ ọrẹ mimu si: ti iwọ si rú ẹbọ ọrẹ jijẹ. Emi ha le gbà itunu ninu wọnyi?

7. Lori oke giga giga ni iwọ fi akete rẹ si, ani nibẹ ni iwọ ti lọ lati rú ẹbọ.

Ka pipe ipin Isa 57