Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 5:6-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Emi o si sọ ọ di ahoro, a kì yio tọ́ ẹka rẹ̀, bẹ̃ni a kì yio wà a, ṣugbọn ẹ̀wọn ati ẹ̀gún ni yio ma hù nibẹ, emi o si paṣẹ fun awọsanma ki o má rọjò sori rẹ̀.

7. Nitori ọ̀gba àjara Oluwa awọn ọmọ-ogun ni ile Israeli, ati awọn ọkunrin Juda ni igi-gbìgbin ti o wù u, o reti idajọ, ṣugbọn kiyesi i, inilara; o si reti ododo; ṣugbọn kiyesi i, igbe.

8. Egbe ni fun awọn ti o ni ile kún ile, ti nfi oko kún oko, titi ãyè kò fi si mọ, ki nwọn bà le nikan wà li ãrin ilẹ aiye!

9. Li eti mi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ pe, Nitõtọ ọ̀pọ ile ni yio di ahoro, ile nla ati daradara laisi olugbe.

10. Nitõtọ ìwọn akeri mẹwa ọ̀gba àjara yio mu òṣuwọn bati kan wá, ati òṣuwọn irugbìn homeri kan yio mu òṣuwọn efa kan wá.

11. Egbe ni fun awọn ti ima dide ni kùtukutu, ki nwọn le ma lepa ọti lile; ti nwọn wà ninu rẹ̀ titi di alẹ, titi ọti-waini mu ara wọn gbona!

12. Ati durù, ati fioli, tabreti, ferè, ati ọti-waini wà ninu àse wọn: ṣugbọn nwọn kò kà iṣẹ Oluwa si, bẹ̃ni nwọn kò rò iṣẹ ọwọ́ rẹ̀.

13. Nitorina awọn enia mi lọ si oko-ẹrú, nitoriti oye kò si, awọn ọlọla wọn di rirù, ati ọ̀pọlọpọ wọn gbẹ fun orùngbẹ.

14. Nitorina ipò-òkú ti fun ara rẹ̀ li àye, o si là ẹnu rẹ̀ li aini ìwọn: ati ogo wọn, ati ọ̀pọlọpọ wọn, ati ọṣọ́ wọn, ati awọn ẹniti nyọ̀, yio sọkalẹ sinu rẹ̀.

15. Enia lasan li a o rẹ̀ silẹ, ati ẹni-alagbara li a o rẹ̀ silẹ, oju agberaga li a o si rẹ̀ silẹ.

16. Ṣugbọn Oluwa awọn ọmọ-ogun li a o gbe ga ni idajọ, ati Ọlọrun Ẹni-Mimọ́ yio jẹ mimọ́ ninu ododo.

17. Nigbana li awọn ọdọ-agutan yio ma jẹ̀ gẹgẹ bi iṣe wọn, ati ibi ahoro awọn ti o sanra li awọn alejò yio ma jẹ.

18. Egbe ni fun awọn ti nfi ohun asan fà ìwa buburu, ati awọn ti o dabi ẹnipe nfi okùn kẹkẹ́ fà ẹ̀ṣẹ.

19. Awọn ti o wipe, Jẹ ki o yara, ki o si mu iṣẹ rẹ̀ yara, ki awa ki o le ri i: ati jẹ ki ìmọ Ẹni-Mimọ́ Israeli sunmọ ihin, ki o si wá, ki awa ki o le mọ̀ ọ.

20. Egbe ni fun awọn ti npè ibi ni rere, ati rere ni ibi, ti nfi okùnkun ṣe imọlẹ, ati imọlẹ ṣe okùnkun: ti nfi ikorò pe adùn, ati adùn pe ikorò!

21. Egbe ni fun awọn ti nwọn gbọ́n li oju ara wọn, ti nwọn si mọ̀ oye li oju ara wọn!

Ka pipe ipin Isa 5