Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 49:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ gbọ ti emi, ẹnyin erekùṣu; ki ẹ si fi etí silẹ, ẹnyin enia lati ọ̀na jijìn wá; Oluwa ti pè mi lati inu wá; lati inu iya mi li o ti dá orukọ mi.

2. O si ti ṣe ẹnu mi bi idà mimú; ninu ojìji ọwọ́ rẹ̀ li o ti pa mi mọ, o si sọ mi di ọfà didán; ninu apó rẹ̀ li o ti pa mi mọ́;

3. O si wi fun mi pe, Iwọ ni iranṣẹ mi, Israeli, ninu ẹniti a o yìn mi logo.

4. Nigbana ni mo wi pe, Emi ti ṣiṣẹ́ lasan, emi ti lò agbara mi lofo, ati lasan: nitõtọ idajọ mi mbẹ lọdọ Oluwa, ati iṣẹ mi lọdọ Ọlọrun mi.

5. Ati nisisiyi, li Oluwa wi, ẹni ti o mọ mi lati inu wá lati ṣe iranṣẹ rẹ̀, lati mu Jakobu pada wá sọdọ rẹ̀, lati ṣà Israeli jọ, ki emi le ni ogo loju Oluwa, Ọlọrun mi yio si jẹ́ agbara mi.

6. O si wipe, O ṣe ohun kekere ki iwọ ṣe iranṣẹ mi, lati gbe awọn ẹyà Jakobu dide, ati lati mu awọn ipamọ Israeli pada: emi o si fi ọ ṣe imọlẹ awọn Keferi, ki iwọ ki o le ṣe igbala mi titi de opin aiye.

7. Bayi ni Oluwa, Olurapada Israeli, ati Ẹni-Mimọ rẹ wi, fun ẹniti enia ngàn, fun ẹniti orilẹ-ède korira, fun iranṣẹ awọn olori, pe, Awọn ọba yio ri, nwọn o si dide, awọn ọmọ-alade pẹlu yio wolẹ sìn, nitori Oluwa ti iṣe olõtọ, Ẹni-Mimọ Israeli, on li o yàn ọ.

8. Bayi ni Oluwa wi, Li akoko itẹwọgba emi ti gbọ́ tirẹ, ati li ọjọ igbala, mo si ti ràn ọ lọwọ: emi o si pa ọ mọ, emi o si fi ọ ṣe majẹmu awọn enia, lati fi idi aiye mulẹ, lati mu ni jogun ahoro ilẹ nini wọnni.

9. Ki iwọ ki o le wi fun awọn igbekùn pe, Ẹ jade lọ; fun awọn ti o wà ni okùnkun pe, Ẹ fi ara nyin hàn. Nwọn o jẹ̀ li ọ̀na wọnni, pápa ijẹ wọn o si wà ni gbogbo ibi giga.

10. Ebi kì yio pa wọn, bẹ̃ni ongbẹ kì yio si gbẹ wọn; õru kì yio mu wọn, bẹ̃ni õrùn kì yio si pa wọn: nitori ẹniti o ti ṣãnu fun wọn yio tọ́ wọn, ani nihà isun omi ni yio dà wọn.

11. Emi o si sọ gbogbo awọn òke-nla mi wọnni di ọ̀na, a o si gbe ọ̀na opopo mi wọnni ga.

12. Kiye si i, awọn wọnyi yio wá lati ọ̀na jijìn: si wò o, awọn wọnyi lati ariwa wá; ati lati iwọ-õrun wá, ati awọn wọnyi lati ilẹ Sinimu wá.

Ka pipe ipin Isa 49