Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 48:1-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. GBỌ́ eyi, ẹnyin ile Jakobu, ti a nfi orukọ Israeli pè, ti o si ti inu omi Juda wọnni jade wá, ti o nfi orukọ Oluwa bura, ti o si ndarukọ Ọlọrun Israeli, ṣugbọn ki iṣe li otitọ, tabi li ododo.

2. Nitori nwọn npè ara wọn ni ti ilu mimọ́ nì, nwọn si gbé ara wọn le Ọlọrun Israeli: Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.

3. Emi ti sọ nkan ti iṣãju wọnni lati ipilẹṣẹ; nwọn si ti jade lati ẹnu mi lọ, emi si fi wọn hàn; emi ṣe wọn lojijì, nwọn si ti ṣẹ.

4. Nitori emi mọ̀ pe olori-lile ni iwọ, ọrùn rẹ jẹ iṣan irin, iwaju rẹ si jẹ idẹ.

5. Li atetekọṣe ni mo tilẹ ti sọ fun ọ; ki o to de ni emi ti fihàn ọ: ki iwọ má ba wipe, Oriṣa mi li o ṣe wọn, ati ere mi gbigbẹ́, ati ere mi didà li o ti pa wọn li aṣẹ.

6. Iwọ ti gbọ́, wò gbogbo eyi; ẹnyin kì yio ha sọ ọ? Emi ti fi ohun titun hàn ọ lati igba yi lọ, ani nkan ti o pamọ́, iwọ kò si mọ̀ wọn.

7. Nisisiyi li a dá wọn, ki isi ṣe li atetekọṣe; ani ṣaju ọjọ na ti iwọ kò gbọ́ wọn; ki iwọ má ba wipe, Kiyesi i, emi mọ̀ wọn.

8. Lõtọ, iwọ kò gbọ́; lõtọ, iwọ kò mọ̀; lõtọ lati igba na eti rẹ̀ kò ṣi: nitori ti emi mọ̀ pe, iwọ o hùwa arekerekè, gidigidi li a si pè ọ li olurekọja lati inu wá.

9. Nitori orukọ mi emi o mu ibinu mi pẹ, ati nitori iyìn mi, emi o fàsẹhin nitori rẹ, ki emi má ba ké ọ kuro.

10. Wò o, emi ti dà ọ, ṣugbọn ki iṣe bi fadaka; emi ti yan ọ ninu iná ileru wahala.

11. Nitori emi tikalami, ani nitori ti emi tikala mi, li emi o ṣe e, nitori a o ha ṣe bà orukọ mi jẹ? emi kì yio si fi ogo mi fun ẹlomiran.

12. Gbọ́ ti emi, iwọ Jakobu, ati Israeli, ẹni-ipè mi; Emi na ni; emi li ẹni-ikini, ati ẹni-ikẹhin.

13. Ọwọ́ mi pẹlu li o si ti fi ipilẹ aiye sọlẹ, atẹlẹwọ ọ̀tun mi li o si na awọn ọrun: nigbati mo pè wọn, nwọn jumọ dide duro.

14. Gbogbo nyin, ẹ pejọ, ẹ si gbọ́; tani ninu wọn ti o ti sọ nkan wọnyi? Oluwa ti fẹ́ ẹ: yio si ṣe ifẹ rẹ̀ ni Babiloni, apá rẹ̀ yio si wà lara awọn ara Kaldea.

15. Emi, ani emi ti sọ ọ; lõtọ emi ti pè e: emi ti mu u wá, on o si mu ọ̀na rẹ̀ ṣe dẽde.

Ka pipe ipin Isa 48