Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 47:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. SỌKALẸ, si joko ninu ekuru, iwọ wundia ọmọbinrin Babiloni, joko ni ilẹ: itẹ́ kò si, iwọ ọmọbinrin ara Kaldea: nitori a kì o pè ọ ni ẹlẹ́gẹ on aláfẹ mọ.

2. Gbe ọlọ, si lọ̀ iyẹfun, ṣi iboju rẹ, ká aṣọ ẹsẹ, ká aṣọ itan, là odo wọnni kọja.

3. A o ṣi ihoho rẹ, a o si ri itiju rẹ pẹlu; emi o gbẹsan, enia kì yio sí lati da mi duro.

4. Olurapada wa, Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀, Ẹni-Mimọ Israeli.

5. Joko, dakẹ jẹ, lọ sinu okùnkun, iwọ ọmọbinrin ara Kaldea, nitori a ki yio pe ọ ni Iyálode awọn ijọba mọ.

6. Emi ti binu si enia mi, emi ti sọ ilẹ ini mi di aimọ́, mo si ti fi wọn le ọ lọwọ: iwọ kò kãnu wọn, iwọ fi ajàga wuwo le awọn alagba lori.

7. Iwọ si wipe, Emi o ma jẹ Iyalode titi lai: bẹ̃ni iwọ kò fi nkan wọnyi si aiya rẹ, bẹ̃ni iwọ kò ranti igbẹhin rẹ.

Ka pipe ipin Isa 47