Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 44:22-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Mo ti pa irekọja rẹ rẹ́, bi awọsanma ṣiṣú dùdu, ati ẹ̀ṣẹ rẹ, bi kũku: yipada sọdọ mi; nitori mo ti rà ọ pada.

23. Kọrin, ẹnyin ọrun; nitori Oluwa ti ṣe e: kigbe, ẹnyin isalẹ aiye; bú si orin, ẹnyin oke-nla, igbó, ati gbogbo igi inu rẹ̀; nitori Oluwa ti rà Jakobu pada, o si ṣe ara rẹ̀ logo ni Israeli.

24. Bayi ni Oluwa, Olurapada rẹ wi, ati ẹniti o mọ ọ lati inu wá: emi li Oluwa ti o ṣe ohun gbogbo; ti o nikan nà awọn ọrun; ti mo si tikara mi tẹ́ aiye.

25. Ẹniti o sọ àmi awọn eke di asan, ti o si bà awọn alafọṣẹ li ori jẹ, ti o dá awọn ọlọgbọn pada, ti o si sọ imọ̀ wọn di wère.

26. Ti o fi ìdi ọ̀rọ iranṣẹ rẹ̀ mulẹ, ti o si mu ìmọ awọn ikọ̀ rẹ̀ ṣẹ; ti o wi fun Jerusalemu pe, A o tẹ̀ ọ dó; ati fun gbogbo ilu Juda pe, A o kọ́ nyin, emi o si gbe gbogbo ahoro rẹ̀ dide:

27. Ti o wi fun ibú pe, Gbẹ, emi o si mu gbogbo odò rẹ gbẹ.

28. Ti o wi niti Kirusi pe, Oluṣọ-agutan mi ni, yío si mu gbogbo ifẹ mi ṣẹ: ti o wi niti Jerusalemu pe, A o kọ́ ọ: ati niti tempili pe, A o fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ.

Ka pipe ipin Isa 44