Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 40:15-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Kiyesi i, awọn orilẹ-ède dabi iró kan ninu omi ladugbo, a si kà wọn bi ekúru kiun ninu ìwọn: kiyesi i, o nmu awọn erekùṣu bi ohun diẹ kiun.

16. Lebanoni kò si tó fi joná, bẹ̃ni awọn ẹranko ibẹ kò to lati fi rubọ sisun.

17. Gbogbo orilẹ-ède li o dabi ofo niwaju rẹ̀; a si kà wọn si fun u bi ohun ti o rẹ̀hin jù ofo ati asan lọ.

18. Tali ẹnyin o ha fi Ọlọrun we? tabi awòran kini ẹnyin o fi ṣe akàwe rẹ̀?

19. Oniṣọ̀na ngbẹ́ ère, alagbẹdẹ wura si nfi wura bò o, o si ndà ẹ̀wọn fadakà.

20. Ẹniti o talakà tobẹ̃ ti kò fi ni ohun ọrẹ, yàn igi ti kì yio rà; o nwá ọlọgbọn oniṣọ̀na fun ara rẹ̀ lati gbẹ́ ère gbigbẹ́ ti a ki yio ṣi nipò.

21. Ẹnyin kò ti mọ̀? ẹnyin kò ti gbọ́? a kò ti sọ fun nyin li atètekọṣe? kò iti yé nyin lati ipilẹṣẹ aiye wá?

22. On ni ẹniti o joko lori òbíri aiye, gbogbo awọn ti ngbe ibẹ si dabi ẹlẹngà; ẹniti o ta ọrun bi ohun tita, ti o si nà wọn bi àgọ lati gbe.

23. Ẹniti o nsọ awọn ọmọ-alade di ofo; o ṣe awọn onidajọ aiye bi asan.

24. Nitõtọ, a kì yio gbìn wọn; nitõtọ, a kì yio sú wọn: nitõtọ igi wọn kì yio fi gbòngbo mulẹ: on o si fẹ́ lù wọn pẹlu, nwọn o si rọ, ãja yio si mu wọn lọ bi akekù koriko.

25. Njẹ tani ẹnyin o ha fi mi we, tabi tali emi o ba dọgbà? ni Ẹni-Mimọ wi.

26. Gbe oju nyin soke sibi giga, ki ẹ si wò, tali o dá nkan wọnyi, ti nmu ogun wọn jade wá ni iye: o npè gbogbo wọn li orukọ nipa titobi ipá rẹ̀, nitoripe on le ni ipá; kò si ọkan ti o kù.

27. Ẽṣe ti iwọ fi nwi, Iwọ Jakobu, ti iwọ si nsọ, Iwọ Israeli pe, Ọ̀na mi pamọ kuro lọdọ Oluwa, idajọ mi si rekọja kuro lọdọ Ọlọrun mi?

28. Iwọ kò ti imọ? iwọ kò ti igbọ́ pe, Ọlọrun aiyeraiye, Oluwa, Ẹlẹda gbogbo ipẹkun aiye, kì iṣãrẹ̀, bẹ̃ni ãrẹ̀ kì imu u? kò si awari oye rẹ̀.

29. O nfi agbara fun alãrẹ̀; o si fi agbara kún awọn ti kò ni ipá.

30. Ani ãrẹ̀ yio mu awọn ọdọmọde, yio si rẹ̀ wọn, ati awọn ọdọmọkunrin yio tilẹ ṣubu patapata:

31. Ṣugbọn awọn ti o ba duro de Oluwa yio tun agbara wọn ṣe; nwọn o fi iyẹ́ gùn oke bi idì; nwọn o sare, kì yio si rẹ̀ wọn; nwọn o rìn, ãrẹ̀ kì yio si mu wọn.

Ka pipe ipin Isa 40