Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 37:23-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Tani iwọ kẹgàn ti o si sọ̀rọ buburu si? tani iwọ si gbe oju rẹ ga si, ti o si gbe oju rẹ soke gangan? si Ẹni-Mimọ́ Israeli ni.

24. Nipasẹ awọn iranṣẹ rẹ li o ti kẹgàn Oluwa, ti o si ti wipe, Ni ọ̀pọlọpọ kẹkẹ́ mi, emi ti goke wá si oke awọn oke giga, si ẹba Lebanoni; emi o si ke igi kedari rẹ̀ giga lulẹ, ati ãyò igi firi rẹ̀, emi o si wá si ẹnu agbègbe rẹ̀, ati si igbó Karmeli rẹ̀.

25. Emi ti wà kanga, mo si ti mu omi; atẹlẹsẹ mi ni mo si ti fi mu gbogbo odò ibi ihamọ gbẹ.

26. Iwọ kò ti gbọ́ ri pe, lai emi li o ti ṣe e, ati pe emi li o ti dá a nigba atijọ? nisisiyi mo mu u ṣẹ, ki iwọ ki o sọ ilu-nla olodi dahoro, di okiti iparun.

27. Nitorina ni awọn olugbé wọn fi ṣe alainipa, aiya fò wọn, nwọn si dãmu: nwọn dabi koriko igbẹ, ati bi ewebẹ̀ tutù, bi koriko lori okè ilé, ati bi ọkà ti igbẹ ki o to dàgba soke.

28. Ṣugbọn mo mọ̀ ibugbe rẹ, ijadelọ rẹ, ati iwọle rẹ, ati irúnu rẹ si mi.

29. Nitori irúnu rẹ si mi, ati igberaga rẹ, ti goke wá si eti mi, nitorina ni emi o ṣe fi ìwọ mi kọ́ ọ ni imú, ati ijanu mi si ète rẹ, emi o si mu ọ pada li ọ̀na ti o ba wá.

Ka pipe ipin Isa 37