Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 37:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe, nigbati Hesekiah ọba gbọ́, o fà aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ ọ̀fọ bora, o si lọ sinu ile Oluwa.

2. O si ran Eliakimu, ti o ṣe olutọju ile, ati Ṣebna akọwe, ati awọn agba alufa ti nwọn fi aṣọ ọ̀fọ bora, sọdọ Isaiah woli, ọmọ Amosi.

3. Nwọn si wi fun u pe, Bayi ni Hesekiah wi, Oni jẹ ọjọ wahalà, ati ibawi, ati ẹgàn: nitori awọn ọmọ de igbà ibí, agbara kò si si lati bí wọn.

4. Bọya Oluwa Ọlọrun rẹ yio gbọ́ ọ̀rọ Rabṣake, ẹniti oluwa rẹ̀ ọba Assiria ti rán lati gàn Ọlọrun alãyè, yio si ba ọ̀rọ ti Oluwa Ọlọrun rẹ ti gbọ́ wi: nitorina gbe adura rẹ soke fun awọn iyokù ti o kù.

5. Bẹ̃ni awọn iranṣẹ Hesekiah ọba wá sọdọ Isaiah.

6. Isaiah si wi fun wọn pe, Bayi ni ki ẹ wi fun oluwa nyin, pe, Bayi ni Oluwa wi, Máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ ti iwọ ti gbọ́, nipa eyiti awọn iranṣẹ ọba Assiria ti fi sọ̀rọ buburu si mi.

7. Wò o, emi o fi ẽmi kan sinu rẹ̀, on o si gbọ́ iró kan, yio si pada si ilu on tikalarẹ̀; emi o si mu ki o ti ipa idà ṣubu ni ilẹ on tikalarẹ̀.

8. Bẹ̃ni Rabṣake padà, o si ba ọba Assiria mba Libna jagun: nitori ti o ti gbọ́ pe o ti kuro ni Lakiṣi.

Ka pipe ipin Isa 37