Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 36:4-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Rabṣake si wi fun wọn pe, Ẹ wi fun Hesekiah nisisiyi, pe, Bayi li ọba nla, ọba Assiria wi, pe, Igbẹkẹle wo ni eyi ti iwọ gbe ara le yi?

5. Iwọ wi pe, Mo ni, (ṣugbọn ọ̀rọ ète lasan ni nwọn) emi ni ìmọ ati agbara fun ogun jija: njẹ tani iwọ tilẹ gbẹkẹle ti iwọ fi nṣọ̀tẹ si mi?

6. Wò o, iwọ gbẹkẹle ọpá iyè fifọ́ yi, le Egipti; eyiti bi ẹnikẹni ba fi ara tì, yio wọnu ọwọ́ rẹ̀, yio si gún u: bẹ̃ni Farao ọba Egipti ri si gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e.

7. Ṣugbọn bi iwọ ba wi fun mi pe, Awa gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun wa: on kọ́ ẹniti Hesekiah ti mu ibi giga rẹ̀ wọnni, ati pẹpẹ rẹ̀, wọnni kuro, ti o si wi fun Juda ati Jerusalemu pe, ẹnyin o ma sìn niwaju pẹpẹ yi?

8. Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, mu ohun-iyàn wá fun oluwa mi ọba Assiria, emi o si fun ọ li ẹgbã ẹṣin, bi iwọ nipa tirẹ ba le ni enia to lati gùn wọn.

9. Njẹ iwọ o ti ṣe le yi oju balogun kan pada ninu awọn ti o rẹhin jù ninu awọn iranṣẹ oluwa mi, ti iwọ si ngbẹkẹ rẹ le Egipti fun kẹkẹ́, ati fun ẹlẹṣin?

10. Emi ha dá goke wá nisisiyi lẹhin Oluwa si ilẹ yi lati pa a run bi? Oluwa wi fun mi pe, Goke lọ si ilẹ yi, ki o si pa a run.

11. Nigbana ni Eliakimu ati Ṣebna ati Joa wi fun Rabṣake pe, Mo bẹ̀ ọ, ba awọn ọmọ-ọdọ rẹ sọ̀rọ li ède Siria, nitori awa gbọ́: má si ṣe ba wa sọ̀rọ li ède Ju, li eti awọn enia ti o wà lori odi.

12. Ṣugbọn Rabṣake wipe, Oluwa mi ha rán mi si oluwa rẹ lati sọ ọ̀rọ wọnyi? kò ha ran mi sọdọ awọn ọkunrin ti o joko lori odi, ki nwọn ki o le ma jẹ igbẹ́ ara wọn, ki nwọn si ma mu ìtọ ara wọn pẹlu nyin?

13. Nigbana ni Rabṣake duro, o si fi ohùn rara kigbe li ède awọn Ju, o si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ ọba nla, ọba Assiria.

Ka pipe ipin Isa 36