Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 36:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si di igbati o ṣe li ọdun ikẹrinla Hesekiah ọba, Sennakeribu ọba Assiria wá dótì gbogbo ilu olodi Juda, o si kó wọn.

2. Ọba Assiria si rán Rabṣake lati Lakiṣi lọ si Jerusalemu, ti on ti ogun nla, sọdọ Hesekiah ọba. O si duro lẹba idari omi abàta oke, li opopo pápa afọṣọ.

3. Nigbana ni Eliakimu ọmọ Hilkia, olùtọ́ju ile, jade tọ̀ ọ wá, pẹlu Ṣebna akọwe, ati Joa ọmọ Asafu, akọwe iranti.

4. Rabṣake si wi fun wọn pe, Ẹ wi fun Hesekiah nisisiyi, pe, Bayi li ọba nla, ọba Assiria wi, pe, Igbẹkẹle wo ni eyi ti iwọ gbe ara le yi?

Ka pipe ipin Isa 36