Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 35:5-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Nigbana li oju awọn afọju yio là, eti awọn aditi yio si ṣi.

6. Nigbana li awọn arọ yio fò bi agbọ̀nrin, ati ahọ́n odi yio kọrin: nitori omi yio tú jade li aginju, ati iṣàn omi ni ijù.

7. Ilẹ yíyan yio si di àbata, ati ilẹ ongbẹ yio di isun omi; ni ibugbé awọn dragoni, nibiti olukuluku dubulẹ, ni o jẹ ọgbà fun ẽsú on iyè.

8. Opopo kan yio si wà nibẹ, ati ọ̀na kan, a o si ma pè e ni, Ọ̀na iwà-mimọ́; alaimọ́ kì yio kọja nibẹ; nitori on o wà pẹlu wọn: awọn èro ọ̀na na, bi nwọn tilẹ jẹ òpe, nwọn kì yio ṣì i.

9. Kiniun kì yio si nibẹ, bẹ̃ni ẹranko buburu kì yio gùn u, a kì yio ri i nibẹ; ṣugbọn awọn ti a ràpada ni yio ma rìn nibẹ:

10. Awọn ẹni-iràpada Oluwa yio padà, nwọn o wá si Sioni ti awọn ti orin, ayọ̀ ainipẹkun yio si wà li ori wọn: nwọn o ri ayọ̀ ati inu didùn gbà, ikãnu on imí-ẹ̀dùn yio si fò lọ.

Ka pipe ipin Isa 35