Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 35:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AGINJU ati ilẹ gbigbẹ yio yọ̀ fun wọn; ijù yio yọ̀, yio si tanna bi lili.

2. Ni titanna yio tanna; yio si yọ̀ ani pẹlu ayọ̀ ati orin: ogo Lebanoni li a o fi fun u, ẹwà Karmeli on Ṣaroni; nwọn o ri ogo Oluwa, ati ẹwà Ọlọrun wa.

3. Ẹ mu ọwọ́ ailera le, ẹ si mu ẽkun ailera lokun.

4. Ẹ sọ fun awọn alailaiyà pe, ẹ tujuka, ẹ má bẹ̀ru: wò o, Ọlọrun nyin o wá ti on ti ẹsan, Ọlọrun ti on ti igbẹsan; on o wá, yio si gbà nyin.

Ka pipe ipin Isa 35