Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 30:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA wipe, egbé ni fun awọn ọlọ̀tẹ ọmọ, ti nwọn gbà ìmọ, ṣugbọn kì iṣe ati ọdọ mi; ti nwọn si mulẹ, ṣugbọn kì iṣe nipa ẹmi mi, ki nwọn ba le fi ẹ̀ṣẹ kún ẹ̀ṣẹ:

2. Ti nwọn nrìn lọ si Egipti, ṣugbọn ti nwọn kò bere li ẹnu mi; lati mu ara wọn le nipa agbara Farao, ati lati gbẹkẹle ojiji Egipti!

3. Nitorina ni agbara Farao yio ṣe jẹ itiju nyin, ati igbẹkẹle ojiji Egipti yio jẹ idãmu nyin.

4. Nitori awọn olori rẹ̀ wá ni Soani, awọn ikọ̀ rẹ̀ de Hanesi.

5. Oju awọn enia kan ti kò li ère fun wọn tilẹ tì wọn, ti kò le ṣe iranwọ, tabi anfani, bikoṣe itiju ati ẹ̀gan pẹlu.

6. Ọ̀rọ-ìmọ niti awọn ẹranko gusu: sinu ilẹ wahala on àrodun, nibiti akọ ati abo kiniun ti wá, pamọlẹ ati ejò-ina ti nfò, nwọn o rù ọrọ̀ wọn li ejika awọn ọmọ kẹtẹkẹtẹ, ati iṣura wọn lori iké awọn ràkumi, sọdọ awọn enia kan ti kò li ère.

7. Egipti yio ṣe iranwọ lasan, kò si ni lari: nitorina ni mo ṣe kigbe pè e ni, Rahabu ti o joko jẹ.

8. Nisisiyi lọ, kọ ọ niwaju wọn si walã kan, si kọ ọ sinu iwe kan, ki o le jẹ fun igbà ti mbọ lai ati lailai:

9. Pe, ọlọ̀tẹ enia ni awọn wọnyi, awọn ọmọ eké, awọn ọmọ ti kò fẹ igbọ́ ofin Oluwa:

10. Ti nwọn wi fun awọn ariran pe, Máṣe riran; ati fun awọn wolĩ pe, Má sọtẹlẹ ohun ti o tọ́ fun wa, sọ nkan didùn fun wa, sọ asọtẹlẹ̀ itanjẹ.

11. Kuro li ọna na, yẹ̀ kuro ni ipa na, mu ki Ẹni-Mimọ Israeli ki o dẹkun kuro niwaju wa.

Ka pipe ipin Isa 30