Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 3:2-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Alagbara ọkunrin, ati jagunjagun, onidajọ, ati wolĩ, ati amoye, ati agbà.

3. Balogun ãdọta, ati ọkunrin ọlọla, ati igbìmọ, ati oniṣọ̀na, ati alasọdùn.

4. Awọn ọmọde li emi o fi ṣe ọmọ-alade wọn, awọn ọmọ-ọwọ ni yio si ma ṣe akoso wọn.

5. A o si ni awọn enia lara, olukuluku lọwọ ẹnikeji, ati olukuluku lọwọ aladugbo rẹ̀; ọmọde yio huwà igberaga si àgba, ati alailọla si ọlọla.

6. Nigbati enia kan yio di arakunrin rẹ̀ ti ile baba rẹ̀ mu, wipe, Iwọ ni aṣọ, mã ṣe alakoso wa, ki o si jẹ ki iparun yi wà labẹ ọwọ́ rẹ.

7. Lọjọ na ni yio bura, wipe, Emi kì yio ṣe alatunṣe; nitori ni ile mi kò si onjẹ tabi aṣọ: máṣe fi emi ṣe alakoso awọn enia.

8. Nitori Jerusalemu di iparun, Juda si ṣubu: nitori ahọn wọn ati iṣe wọn lòdi si Oluwa, lati mu oju ogo rẹ̀ binu.

9. Iwò oju wọn njẹri si wọn; nwọn si nfi ẹ̀ṣẹ wọn hàn bi Sodomu, nwọn kò pa a mọ. Egbe ni fun ọkàn wọn! nitori nwọn ti fi ibi san a fun ara wọn.

10. Ẹ sọ fun olododo pe, yio dara fun u: nitori nwọn o jẹ eso iṣe wọn.

11. Egbe ni fun enia buburu! yio buru fun u: nitori ere ọwọ́ rẹ̀ li a o fi fun u.

12. Niti awọn enia mi awọn ọmọde ni aninilara wọn, awọn obinrin si njọba wọn. A! enia mi, awọn ti nyẹ ọ si mu ọ ṣìna, nwọn si npa ipa-ọ̀na rẹ run.

13. Oluwa dide duro lati wijọ, o si dide lati da awọn enia li ẹjọ.

14. Oluwa yio ba awọn agbà enia rẹ̀ lọ sinu idajọ, ati awọn ọmọ-alade inu wọn: nitori ẹnyin ti jẹ ọ̀gba àjara nì run: ẹrù awọn talakà mbẹ ninu ile nyin.

15. Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Kili ẹnyin rò ti ẹ fi fọ́ awọn enia mi tutu, ti ẹ si fi oju awọn talakà rinlẹ?

16. Pẹlupẹlu Oluwa wipe, Nitori awọn ọmọbinrin Sioni gberaga, ti nwọn si nrìn pẹlu ọrùn giga ati oju ifẹkufẹ, ti nwọn nrìn ti nwọn si nyan bi nwọn ti nlọ, ti nwọn si njẹ ki ẹsẹ wọn ró woro:

Ka pipe ipin Isa 3