Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 3:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. KIYESI i, Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun, mu idaduro ati ọpá kuro ninu Jerusalemu ati Juda, gbogbo idaduro onjẹ, ati gbogbo idaduro omi.

2. Alagbara ọkunrin, ati jagunjagun, onidajọ, ati wolĩ, ati amoye, ati agbà.

3. Balogun ãdọta, ati ọkunrin ọlọla, ati igbìmọ, ati oniṣọ̀na, ati alasọdùn.

4. Awọn ọmọde li emi o fi ṣe ọmọ-alade wọn, awọn ọmọ-ọwọ ni yio si ma ṣe akoso wọn.

5. A o si ni awọn enia lara, olukuluku lọwọ ẹnikeji, ati olukuluku lọwọ aladugbo rẹ̀; ọmọde yio huwà igberaga si àgba, ati alailọla si ọlọla.

6. Nigbati enia kan yio di arakunrin rẹ̀ ti ile baba rẹ̀ mu, wipe, Iwọ ni aṣọ, mã ṣe alakoso wa, ki o si jẹ ki iparun yi wà labẹ ọwọ́ rẹ.

Ka pipe ipin Isa 3