Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 27:6-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Yio mu ki awọn ti o ti Jakobu wá ta gbòngbo: Israeli yio tanna yio si rudi, yio si fi eso kún oju gbogbo aiye.

7. On ha lù u bi o ti nlu awọn ti o lù u? a ha pa a gẹgẹ bi pipa awọn ti on pa?

8. Niwọ̀n-niwọ̀n, nigba itìjade rẹ̀, iwọ o ba a wi: on ṣi ẹfũfu-ile rẹ̀ ni ipò li ọjọ ẹfũfu ilà-õrun.

9. Nitorina nipa eyi li a o bò ẹ̀ṣẹ Jakobu mọlẹ: eyi si ni gbogbo eso lati mu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ kuro; nigbati on gbe okuta pẹpẹ kalẹ bi okuta ẹfun ti a lù wẹwẹ, igbó ati ere-õrun kì yio dide duro.

10. Nitori ilu-olodi yio di ahoro, a o si kọ̀ ibugbé silẹ, a o si fi i silẹ bi aginju: nibẹ ni ọmọ-malu yio ma jẹ̀, nibẹ ni yio si dubulẹ, yio si jẹ ẹka rẹ̀ run.

11. Nigbati ẹka inu rẹ̀ ba rọ, a o ya wọn kuro: awọn obinrin de, nwọn si tẹ̀ iná bọ̀ wọn: nitori alaini oye enia ni nwọn: nitorina ẹniti o dá wọn kì yio ṣãnu fun wọn, ẹniti o si mọ wọn kì yio fi ojurere hàn wọn.

12. Yio si ṣe li ọjọ na, Oluwa yio ja eso kuro ni ibu odò si iṣàn Egipti, a o si ṣà nyin jọ li ọkọkan, ẹnyin ọmọ Israeli.

13. Yio si ṣe li ọjọ na, a o fun ipè nla, awọn ti o mura lati ṣegbe ni ilẹ Assiria yio si wá, ati awọn aṣátì ilẹ Egipti, nwọn o si sìn Oluwa ni oke mimọ́ ni Jerusalemu.

Ka pipe ipin Isa 27