Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 27:3-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Emi Oluwa li o ṣọ ọ: emi o bù omi wọ́n ọ nigbakugba: ki ẹnikẹni má ba bà a jẹ, emi o ṣọ ọ ti oru ti ọsan.

4. Irunú kò si ninu mi: tani le doju pantiri ẹlẹgun ati ẹgun kọ mi li ogun jijà? emi iba là wọn kọja, emi iba fi wọn jona pọ̀ ṣọ̀kan.

5. Tabi jẹ ki o di agbara mi mu, ki o ba le ba mi lajà; yio si ba mi lajà.

6. Yio mu ki awọn ti o ti Jakobu wá ta gbòngbo: Israeli yio tanna yio si rudi, yio si fi eso kún oju gbogbo aiye.

7. On ha lù u bi o ti nlu awọn ti o lù u? a ha pa a gẹgẹ bi pipa awọn ti on pa?

8. Niwọ̀n-niwọ̀n, nigba itìjade rẹ̀, iwọ o ba a wi: on ṣi ẹfũfu-ile rẹ̀ ni ipò li ọjọ ẹfũfu ilà-õrun.

9. Nitorina nipa eyi li a o bò ẹ̀ṣẹ Jakobu mọlẹ: eyi si ni gbogbo eso lati mu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ kuro; nigbati on gbe okuta pẹpẹ kalẹ bi okuta ẹfun ti a lù wẹwẹ, igbó ati ere-õrun kì yio dide duro.

10. Nitori ilu-olodi yio di ahoro, a o si kọ̀ ibugbé silẹ, a o si fi i silẹ bi aginju: nibẹ ni ọmọ-malu yio ma jẹ̀, nibẹ ni yio si dubulẹ, yio si jẹ ẹka rẹ̀ run.

Ka pipe ipin Isa 27