Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 24:6-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Nitorina ni egún ṣe jẹ ilẹ run, awọn ti ngbe inu rẹ̀ di ahoro: nitorina ni awọn ti ngbe ilẹ jona, enia diẹ li o si kù.

7. Ọti-waini titun nṣọ̀fọ, àjara njoro, gbogbo awọn ti nṣe aríya nkẹdùn.

8. Ayọ̀ tabreti dá, ariwo awọn ti nyọ̀ pin, ayọ̀ harpu dá.

9. Nwọn kì yio fi orin mu ọti-waini mọ́; ọti-lile yio koro fun awọn ti nmu u.

10. A wó ilu rúdurudu palẹ: olukuluku ile li a se, ki ẹnikan má bà wọle.

11. Igbe fun ọti-waini mbẹ ni igboro; gbogbo ayọ̀ ṣú òkunkun, aríya ilẹ na lọ.

12. Idahoro li o kù ni ilu, a si fi iparun lù ẹnu-ibode.

13. Nigbati yio ri bayi li ãrin ilẹ lãrin enia na, bi mimì igi olifi, ati bi pipẽṣẹ eso-àjara nigbati ikorè àjara tán.

14. Nwọn o gbe ohùn wọn soke, nwọn o kọrin nitori ọla-nla Oluwa, nwọn o kigbe kikan lati okun wá.

15. Nitorina yìn Oluwa li ogo ni ilẹ imọlẹ, ani orukọ Oluwa Ọlọrun Israeli li erekùṣu okun.

16. Lati opin ilẹ li awa ti gbọ́ orin, ani ogo fun olododo. Ṣugbọn emi wipe, Iparun mi, iparun mi, egbé ni fun mi! awọn ọ̀dalẹ ti dalẹ: nitõtọ, awọn ọ̀dalẹ dalẹ rekọja.

Ka pipe ipin Isa 24