Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 24:12-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Idahoro li o kù ni ilu, a si fi iparun lù ẹnu-ibode.

13. Nigbati yio ri bayi li ãrin ilẹ lãrin enia na, bi mimì igi olifi, ati bi pipẽṣẹ eso-àjara nigbati ikorè àjara tán.

14. Nwọn o gbe ohùn wọn soke, nwọn o kọrin nitori ọla-nla Oluwa, nwọn o kigbe kikan lati okun wá.

15. Nitorina yìn Oluwa li ogo ni ilẹ imọlẹ, ani orukọ Oluwa Ọlọrun Israeli li erekùṣu okun.

16. Lati opin ilẹ li awa ti gbọ́ orin, ani ogo fun olododo. Ṣugbọn emi wipe, Iparun mi, iparun mi, egbé ni fun mi! awọn ọ̀dalẹ ti dalẹ: nitõtọ, awọn ọ̀dalẹ dalẹ rekọja.

17. Ibẹ̀ru, ati ọ̀fin, ati ẹgẹ́, wà lori rẹ, iwọ ti ngbe ilẹ-aiye.

18. Yio si ṣe, ẹniti o sá kuro fun ariwo ìbẹru yio jin sinu ọ̀fin; ati ẹniti o jade lati inu ọ̀fin wá li a o fi ẹgẹ́ mu: nitori awọn ferese lati oke wá ṣi silẹ, ipilẹ ilẹ si mì.

19. Ilẹ di fifọ́ patapata, ilẹ di yíyọ patapata, ilẹ mì tìtì.

20. Ilẹ yio ta gbọ̀ngbọn sihin sọhun bi ọ̀mutí, a o si ṣi i ni idí bi agọ́; irekọja inu rẹ̀ yio wọ̀ ọ li ọrùn; yio si ṣubu, kì yio si dide mọ́.

21. Yio si ṣe li ọjọ na, Oluwa yio bẹ̀ ogun awọn ẹni-giga ni ibi-giga wò, ati awọn ọba aiye li aiye.

Ka pipe ipin Isa 24