Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 2:14-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Ati lori gbogbo òke giga, ati lori gbogbo òke kékèké ti a gbe soke.

15. Ati lori gbogbo ile-iṣọ giga ati lori gbogbo odi,

16. Ati lori gbogbo ọkọ̀ Tarṣiṣi, ati lori gbogbo awòran ti o wuni,

17. A o si tẹ̀ ori igberaga enia balẹ, irera awọn enia li a o si rẹ̀ silẹ; Oluwa nikanṣoṣo li a o gbega li ọjọ na.

18. Awọn òriṣa ni yio si parun patapata.

19. Nwọn o si wọ̀ inu ihò apata lọ, ati inu ihò ilẹ, nitori ìbẹru Oluwa, ati nitori ogo ọlanla rẹ̀, nigbati o ba dide lati mì ilẹ aiye kijikiji.

20. Li ọjọ na, enia yio jù òriṣa fadakà rẹ̀, ati òriṣa wurà rẹ̀, ti nwọn ṣe olukuluku wọn lati ma bọ, si ekute ati si àdan,

21. Lati lọ sinu pàlapala apata, ati soke apata sisán, nitori ibẹru Oluwa, ati nitori ogo ọlanla rẹ̀; nigbati o ba dide lati mì ilẹ aiye kijikiji.

22. Ẹ simi lẹhìn enia, ẹmi ẹniti o wà ni ihò imu rẹ̀; nitori ninu kini a le kà a si?

Ka pipe ipin Isa 2