Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 2:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ ti Isaiah ọmọ Amosi ri nipa Juda ati Jerusalemu.

2. Yio si ṣe ni ọjọ ikẹhìn, a o fi òke ile Oluwa kalẹ lori awọn òke nla, a o si gbe e ga ju awọn òke kékèké lọ; gbogbo orilẹ-ède ni yio si wọ́ si inu rẹ̀.

3. Ọ̀pọlọpọ enia ni yio si lọ, nwọn o si wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a lọ si òke Oluwa, si ile Ọlọrun Jakobu; On o si kọ́ wa li ọ̀na rẹ̀, awa o si ma rìn ni ipa rẹ̀; nitori lati Sioni ni ofin yio ti jade lọ, ati ọ̀rọ Oluwa lati Jerusalemu.

4. On o si dajọ lãrin awọn orilẹ-ède, yio si ba ọ̀pọlọpọ enia wi: nwọn o fi idà wọn rọ ọbẹ-plau, nwọn o si fi ọ̀kọ wọn rọ dojé; orilẹ-ède kì yio gbe idà soke si orilẹ-ède; bẹ̃ni nwọn kì yio kọ́ ogun jijà mọ.

5. Ara ile Jakobu, ẹ wá, ẹ jẹ́ ka rìn ninu imọlẹ Ọluwa.

6. Nitorina ni iwọ ṣe kọ̀ awọn enia rẹ, ile Jakobu silẹ̀; nitoriti nwọn kún lati ìla ọ̀run wá, nwọn jẹ alafọ̀ṣẹ bi awọn ara Filistia, nwọn si nṣe inu didùn ninu awọn ọmọ alejò.

7. Ilẹ wọn pẹlu kún fun fadakà ati wurà; bẹ̃ni kò si opin fun iṣura wọn; ilẹ wọn si kun fun ẹṣin, bẹ̃ni kò si opin fun kẹkẹ́ ogun wọn.

8. Ilẹ wọn kún fun oriṣa pẹlu; nwọn mbọ iṣẹ ọwọ́ ara wọn, eyiti ika awọn tikalawọn ti ṣe.

9. Enia lasan si foribalẹ, ẹni-nla si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ; nitorina má ṣe darijì wọn.

Ka pipe ipin Isa 2