Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 17:7-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Li ọjọ na li ẹnikan yio wò Ẹlẹda rẹ̀, ati oju rẹ̀ yio si bọ̀wọ fun Ẹni-Mimọ Israeli.

8. On kì yio si wò pẹpẹ, iṣẹ ọwọ́ rẹ̀, bẹ̃ni kì yio si bọ̀wọ fun eyi ti ika rẹ̀ ti ṣe, yala igbo-òriṣa tabi ere-õrun.

9. Li ọjọ na ni ilu alagbara rẹ̀ yio dabi ẹka ìkọsilẹ, ati ẹka tente oke ti nwọn fi silẹ nitori awọn ọmọ Israeli: iparun yio si wà.

10. Nitori iwọ ti gbagbe Ọlọrun igbala rẹ, ti iwọ kò si nani apata agbára rẹ, nitorina ni iwọ ti gbìn ọ̀gbin daradara, iwọ si tọ́ àjeji ẹka sinu rẹ̀.

11. Li ọjọ na ni iwọ o mu ki ọ̀gbin rẹ dàgba, ati li owurọ ni iwọ o mu ki irugbin rẹ rú: ṣugbọn a o mu ikorè lọ li ọjọ ini, ikãnu kikoro yio si wà.

12. Egbé ni fun ariwo ọ̀pọ enia, ti o pa ariwo bi ariwo okun; ati fun irọ́ awọn orilẹ-ède, ti nwọn rọ bi rirọ́ omi pupọ̀!

13. Awọn orilẹ-ède yio rọ́ bi rirọ́ omi pupọ: ṣugbọn Ọlọrun yio bá wọn wi, nwọn si sa jina rere, a o si lepa wọn gẹgẹ bi ìyangbo oke-nla niwaju ẹfũfu, ati gẹgẹ bi ohun yiyi niwaju ãjà.

14. Si kiye si i, li aṣalẹ, iyọnu; ki ilẹ to mọ́ on kò si. Eyi ni ipín awọn ti o kó wa, ati ipín awọn ti o jà wa li olè.

Ka pipe ipin Isa 17