Awọn orilẹ-ède yio rọ́ bi rirọ́ omi pupọ: ṣugbọn Ọlọrun yio bá wọn wi, nwọn si sa jina rere, a o si lepa wọn gẹgẹ bi ìyangbo oke-nla niwaju ẹfũfu, ati gẹgẹ bi ohun yiyi niwaju ãjà.