Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 17:11-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Li ọjọ na ni iwọ o mu ki ọ̀gbin rẹ dàgba, ati li owurọ ni iwọ o mu ki irugbin rẹ rú: ṣugbọn a o mu ikorè lọ li ọjọ ini, ikãnu kikoro yio si wà.

12. Egbé ni fun ariwo ọ̀pọ enia, ti o pa ariwo bi ariwo okun; ati fun irọ́ awọn orilẹ-ède, ti nwọn rọ bi rirọ́ omi pupọ̀!

13. Awọn orilẹ-ède yio rọ́ bi rirọ́ omi pupọ: ṣugbọn Ọlọrun yio bá wọn wi, nwọn si sa jina rere, a o si lepa wọn gẹgẹ bi ìyangbo oke-nla niwaju ẹfũfu, ati gẹgẹ bi ohun yiyi niwaju ãjà.

14. Si kiye si i, li aṣalẹ, iyọnu; ki ilẹ to mọ́ on kò si. Eyi ni ipín awọn ti o kó wa, ati ipín awọn ti o jà wa li olè.

Ka pipe ipin Isa 17