Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 15:4-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Heṣboni yio si kigbe, ati Eleale: a o si gbọ́ ohùn wọn titi dé Jahasi: nitorina ni awọn ọmọ-ogun Moabu ti o hamọra yio kigbe soke; ọkàn rẹ̀ yio bajẹ fun ara rẹ̀.

5. Ọkàn mi kigbe soke fun Moabu; awọn ìsánsá rẹ̀ sá de Soari, abo-malũ ọlọdun mẹta: ni gigun oke Luhiti tẹkúntẹkún ni nwọn o ma fi gùn u lọ; niti ọ̀na Horonaimu nwọn o gbe ohùn iparun soke.

6. Nitori awọn omi Nimrimu yio di ahoro: nitori koriko nrọgbẹ, eweko nkú lọ, ohun tutù kan kò si.

7. Nitorina ọ̀pọ eyi ti nwọn ti ni, ati eyi ti nwọn ti kojọ, ni nwọn o gbe kọja odò willo.

8. Nitori igbe na ti yi agbegbè Moabu ka; igbe na si de Eglaimu, ati igbe na de Beerelimu.

9. Nitori odò Dimoni yio kún fun ẹ̀jẹ: nitori emi o fi ibi miran sori Dimoni, emi o mu kiniun wá sori ẹniti ó sálà kuro ni Moabu, ati lori awọn ti o kù ni ilẹ na.

Ka pipe ipin Isa 15