Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 1:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. IRAN Isaiah ọmọ Amosi, ti o rí nipa Juda ati Jerusalemu li ọjọ Ussiah, Jotamu, Ahasi, ati Hesekiah, awọn ọba Juda.

2. Gbọ́, ẹnyin ọrun, si fi eti silẹ, iwọ aiye: nitori Oluwa ti sọ̀rọ, emi ti bọ́, emi si ti tọ́ awọn ọmọ, nwọn si ti ṣọ̀tẹ si mi.

3. Malũ mọ̀ oluwa rẹ̀, kẹtẹ́kẹtẹ si mọ̀ ibujẹ oluwa rẹ̀: ṣugbọn Israeli kò mọ̀, awọn enia mi kò ronu.

4. A! orilẹ-ède ti o kún fun ẹ̀ṣẹ, enia ti ẹrù ẹ̀ṣẹ npa, irú awọn oluṣe buburu, awọn ọmọ ti iṣe olubajẹ: nwọn ti kọ̀ Oluwa silẹ, nwọn ti mu Ẹni-Mimọ́ Israeli binu, nwọn si ti yipada sẹhìn.

5. Ẽṣe ti a o fi lù nyin si i mọ? ẹnyin o ma ṣọ̀tẹ siwaju ati siwaju: gbogbo ori li o ṣaisàn, gbogbo ọkàn li o si dakú.

6. Lati atẹlẹ̀sẹ titi fi de ori kò si ilera ninu rẹ̀; bikòṣe ọgbẹ́, ipalara, ati õju ti nrà: nwọn kò iti pajumọ, bẹ̃ni a kò iti dì wọn, bẹ̃ni a kò si ti ifi ororo kùn wọn.

7. Ilẹ nyin di ahoro, a fi iná kun ilu nyin: ilẹ nyin, alejo jẹ ẹ run li oju nyin, o si di ahoro, bi eyiti awọn alejo wó palẹ.

8. Ọmọbinrin Sioni li a si fi silẹ bi agọ ninu ọgbà àjara, bi abule ninu ọgbà ẹ̀gúsí, bi ilu ti a dóti.

9. Bikòṣe bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti fi iyokù diẹ kiun silẹ fun wa, awa iba ti dabi Sodomu, awa iba si ti dabi Gomorra.

10. Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin olori Sodomu; fi eti si ofin Ọlọrun wa, ẹnyin enia Gomorra.

11. Oluwa ni, kini ọ̀pọlọpọ ẹbọ nyin jasi fun mi? emi kún fun ọrẹ sisun agbò, ati fun ọrá ẹran abọ́pa; bẹ̃ni emi kò si ni inu didùn si ẹjẹ akọ malũ, tabi si ti ọdọ-agutan, tabi si ti obúkọ.

Ka pipe ipin Isa 1