Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 9:9-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. O si fun ọba li ọgọfa talenti wura, ati turari lọpọlọpọ, ati okuta iyebiye: bẹ̃ni kò ti isi iru turari gẹgẹ bi eyiti ayaba Ṣeba fun Solomoni ọba.

10. Awọn iranṣẹ Huramu pẹlu, ati awọn iranṣẹ Solomoni ti o mu wura Ofiri wá, si mu igi-algumu, ati okuta iyebiye wá pẹlu.

11. Ọba si fi igi-algumu na ṣe àtẹgun ni ile Oluwa, ati ni ile ọba, ati duru ati ohun ọ̀na-orin fun awọn akọrin: a kò si ri iru bẹ̃ ri ni ilẹ Juda.

12. Solomoni ọba si fun ayaba Ṣeba li ohun gbogbo ti o wù u, ohunkohun ti o bère, li aika eyiti o mu wa fun ọba. Bẹ̃ni o yipada, o si lọ si ilẹ rẹ̀, ati on ati awọn iranṣẹ rẹ̀.

13. Njẹ nisisiyi ìwọn wura ti o de fun Solomoni li ọdun kan ni ọtalelẹgbẹta o le mẹfa talenti wura.

14. Laika eyiti awọn oniṣowo ati awọn èro mu wá. Ati awọn ọba Arabia, ati awọn bãlẹ ilẹ na nmu wura ati fadakà tọ̀ Solomoni wá.

15. Solomoni ọba si ṣe igba asà wura lilù: asà kan gba ẹgbẹta ṣekeli wura lilù.

16. Ọdunrun apata wura lilù li o si ṣe; apata kan gbà ọ̃dunrun ṣekeli wura: ọba si fi wọn sinu ile igbo Lebanoni.

17. Ọba si ṣe itẹ́ ehin-erin nla kan, o si fi wura daradara bò o.

Ka pipe ipin 2. Kro 9