Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 9:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBATI ayaba Ṣeba gbọ́ òkiki Solomoni, o wá lati fi àlọ dan Solomoni wò ni Jerusalemu, pẹlu ẹgbẹ́ nlanla, ati ibakasiẹ ti o ru turari, ati wura li ọ̀pọlọpọ ati okuta iyebiye; nigbati o si de ọdọ Solomoni, o ba a sọ ohun gbogbo ti o wà li ọkàn rẹ̀.

2. Solomoni si dahùn gbogbo ibère rẹ̀: kò si si ohun kan ti o pamọ fun Solomoni ti kò sọ fun u,

3. Nigbati ayaba Ṣeba si ti ri ọgbọ́n Solomoni, ati ile ti o ti kọ́,

4. Ati onjẹ tabili rẹ̀, ati ijoko awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ati iduro awọn iranṣẹ rẹ̀, ati aṣọ-wiwọ̀ wọn; ati awọn agbọti rẹ̀ pẹlu aṣọ-wiwọ̀ wọn, ati àtẹgun ti o mba gòke lọ si ile Oluwa; kò si kù agbara kan ninu rẹ̀ mọ.

5. O si wi fun ọba pe, otitọ ni ọ̀rọ ti mo gbọ́ ni ilẹ mi niti iṣe rẹ, ati ọgbọ́n rẹ:

6. Ṣugbọn emi kò gba ọ̀rọ wọn gbọ́, titi mo fi de, ti oju mi si ti ri i; si kiyesi i, a kò rò idaji titobi ọgbọ́n rẹ fun mi; nitori ti iwọ kọja òkiki ti mo ti gbọ́.

7. Ibukún ni fun awọn enia rẹ, ibukún si ni fun awọn iranṣẹ rẹ wọnyi, ti nduro nigbagbogbo niwaju rẹ, ti o si ngbọ́ ọgbọ́n rẹ.

8. Olubukún li Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o fẹran rẹ lati gbé ọ ka ori itẹ́ rẹ̀ lati ṣe ọba fun Oluwa Ọlọrun rẹ: nitoriti Ọlọrun rẹ fẹran Israeli lati fi idi wọn kalẹ lailai, nitorina ni o ṣe fi ọ jọba lori wọn, lati ṣe idajọ ati otitọ.

9. O si fun ọba li ọgọfa talenti wura, ati turari lọpọlọpọ, ati okuta iyebiye: bẹ̃ni kò ti isi iru turari gẹgẹ bi eyiti ayaba Ṣeba fun Solomoni ọba.

10. Awọn iranṣẹ Huramu pẹlu, ati awọn iranṣẹ Solomoni ti o mu wura Ofiri wá, si mu igi-algumu, ati okuta iyebiye wá pẹlu.

11. Ọba si fi igi-algumu na ṣe àtẹgun ni ile Oluwa, ati ni ile ọba, ati duru ati ohun ọ̀na-orin fun awọn akọrin: a kò si ri iru bẹ̃ ri ni ilẹ Juda.

12. Solomoni ọba si fun ayaba Ṣeba li ohun gbogbo ti o wù u, ohunkohun ti o bère, li aika eyiti o mu wa fun ọba. Bẹ̃ni o yipada, o si lọ si ilẹ rẹ̀, ati on ati awọn iranṣẹ rẹ̀.

13. Njẹ nisisiyi ìwọn wura ti o de fun Solomoni li ọdun kan ni ọtalelẹgbẹta o le mẹfa talenti wura.

Ka pipe ipin 2. Kro 9