Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 8:14-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. O si yàn ipa awọn alufa, gẹgẹ bi ilana Dafidi baba rẹ̀, si ìsin wọn, ati awọn ọmọ Lefi si iṣẹ wọn, lati ma yìn, ati lati ma ṣe iranṣẹ niwaju awọn alufa, bi ilana ojojumọ: ati awọn adèna pẹlu ni ipa ti wọn li olukuluku ẹnu-ọ̀na: nitori bẹ̃ni Dafidi, enia Ọlọrun, ti pa a li aṣẹ.

15. Nwọn kò si yà kuro ninu ilana ọba nipa ti awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi niti olukuluku ọ̀ran, ati niti iṣura.

16. Gbogbo iṣẹ Solomoni li a ti pese silẹ bayi de ọjọ ifi-ipilẹ ile Oluwa le ilẹ titi o fi pari. A si pari ile Oluwa.

17. Nigbana ni Solomoni lọ si Esion-Geberi, ati si Eloti, ati si eti okun ni ilẹ Edomu.

18. Huramu si fi ọkọ̀ ranṣẹ si i, nipa ọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn iranṣẹ ti o moye okun; nwọn si ba awọn iranṣẹ Solomoni lọ si Ofiri, lati ibẹ ni nwọn mu ãdọta-le-ni-irinwo talenti wura wá, nwọn si mu wọn tọ̀ Solomoni ọba wá.

Ka pipe ipin 2. Kro 8