Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 8:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe lẹhin ogun ọdun ninu eyi ti Solomoni kọ́ ile Oluwa, ati ile on tikararẹ̀.

2. Ni Solomoni kọ́ ilu wọnni ti Huramu fi fun Solomoni, o si mu ki awọn ọmọ Israeli ki o ma gbe ibẹ.

3. Solomoni si lọ si Hamati-Soba, o si bori rẹ̀.

4. O si kọ́ Tadmori li aginju, ati gbogbo ilu iṣura ti o kọ́ ni Hamati.

5. O kọ́ Bet-Horoni ti òke pẹlu, ati Bet-Horoni ti isalẹ, ilu odi, pẹlu ogiri, ilẹkun, ati ọpa-idabu;

6. Ati Baalati, ati gbogbo ilu iṣura ti Solomoni ni, ati gbogbo ilu kẹkẹ́, ati ilu ẹlẹṣin, ati gbogbo eyiti Solomoni fẹ lati kọ́ ni Jerusalemu, ati ni Lebanoni ati ni gbogbo ilẹ ijọba rẹ̀.

7. Gbogbo awọn enia ti o kù ninu awọn ara Hitti, ati awọn Amori, ati awọn Peresi, ati awọn Hifi ati awọn Jebusi, ti kì iṣe ti inu ọmọ Israeli.

8. Ninu awọn ọmọ wọn, ti a ṣẹkù silẹ lẹhin wọn ni ilẹ na, ti awọn ọmọ Israeli kò run kuro, awọn ni Solomoni bu iṣẹ-ìrú fun titi o fi di oni yi.

9. Ṣugbọn ninu awọn ọmọ Israeli ni Solomoni kò fi ṣe ọmọ-ọdọ fun iṣẹ rẹ̀; nitori awọn li ọga-ogun ati olori awọn onikẹkẹ́ rẹ̀ ati awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀.

10. Awọn wọnyi li olori awọn alaṣẹ Solomoni ọba, adọtalerugba ti nṣakoso lori awọn enia.

11. Solomoni si mu ọmọbinrin Farao gòke lati ilu Dafidi wá si ile ti o kọ́ fun u; nitori ti o wipe, Ni temi, obinrin kan kì yio gbe inu ile Dafidi, ọba Israeli, nitori mimọ́ ni ibi ti apoti-ẹri Oluwa ti de.

Ka pipe ipin 2. Kro 8