Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 7:8-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Li akokò na pẹlu Solomoni se àse na ni ijọ meje, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, ijọ enia nlanla, lati ìwọ Hamati titi de odò Egipti.

9. Ati li ọjọ kẹjọ nwọn ṣe apejọ mimọ́; nitori ti nwọn ṣe ìyasi-mimọ́ pẹpẹ na li ọjọ meje, ati àse na, ọjọ meje.

10. Ati li ọjọ kẹtalelogun oṣù keje, o rán awọn enia pada lọ sinu agọ wọn, pẹlu ayọ̀ ati inudidùn nitori ore-ọfẹ ti Oluwa ti fi hàn fun Dafidi, ati fun Solomoni, ati fun Israeli, enia rẹ̀.

11. Solomoni si pari ile Oluwa, ati ile ọba, ati gbogbo ohun ti o wá si ọkàn Solomoni lati ṣe ninu ile Oluwa, ati ninu ile on tikararẹ̀, o si ṣe e jalẹ.

12. Oluwa si fi ara hàn Solomoni li oru, o si wi fun u pe, Emi ti gbọ́ adura rẹ, emi si ti yàn ihinyi fun ara mi, fun ile ẹbọ.

13. Bi mo ba sé ọrun ti kò ba si òjo, tabi bi emi ba paṣẹ fun eṣú lati jẹ ilẹ na run, tabi bi mo ba rán àjakalẹ-arun si ãrin awọn enia mi;

Ka pipe ipin 2. Kro 7