Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 6:37-42 Yorùbá Bibeli (YCE)

37. Ṣugbọn, bi nwọn ba rò inu ara wọn wò, ni ilẹ nibiti a gbe kó wọn ni igbekun lọ, ti nwọn ba si yipada, ti nwọn ba si gbadura si ọ li oko ẹrú wọn, wipe, Awa ti dẹṣẹ, awa ti ṣìṣe, awa si ti ṣe buburu;

38. Bi nwọn ba si fi gbogbo aiya ati gbogbo ọkàn wọn yipada si ọ li oko ẹrú wọn, si ibi ti a gbe kó wọn lọ, ti nwọn ba si gbadura siha ilẹ wọn, ti iwọ ti fi fun awọn baba wọn, ati siha ilu na ti iwọ ti yàn, ati siha ile na ti emi ti kọ́ fun orukọ rẹ:

39. Ki iwọ ki o gbọ́ adura wọn ati ẹ̀bẹ wọn lati ọrun wá, ani lati ibugbe rẹ wá, ki o si mu ọ̀ran wọn duro, ki o si dari ẹ̀ṣẹ awọn enia rẹ jì ti nwọn ti da si ọ.

40. Nisisiyi Ọlọrun mi, jẹ ki oju rẹ ki o ṣí, ki o si tẹtisilẹ si adura si ihinyi.

41. Njẹ nisisiyi, dide, Oluwa Ọlọrun si ibi isimi rẹ, iwọ ati apoti agbara rẹ; jẹ ki a fi igbala wọ̀ awọn alufa rẹ, Oluwa Ọlọrun, ki o si jẹ ki awọn enia ayanfẹ rẹ ki o ma yọ̀ ninu ire.

42. Oluwa Ọlọrun, máṣe yi oju ẹni ororo rẹ pada: ranti ãnu fun Dafidi, iranṣẹ rẹ.

Ka pipe ipin 2. Kro 6