Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 6:18-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Ni otitọ ni Ọlọrun yio ha ma ba enia gbe li aiye? Kiyesi i, ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà ọ; ambọsi ile yi ti emi kọ́!

19. Sibẹ, iwọ ṣe afiyesi adura iranṣẹ rẹ, ati ẹ̀bẹ rẹ̀, Oluwa Ọlọrun mi, lati tẹtisilẹ si ẹkun ati adura ti iranṣẹ rẹ ngbà niwaju rẹ:

20. Ki oju rẹ ki o le ṣí si ile yi lọsan ati loru, ani si ibi ti iwọ ti wipe, iwọ o fi orukọ rẹ sibẹ; lati tẹtisilẹ si adura ti iranṣẹ rẹ ngbà si ibi yi.

21. Nitorina gbọ́ ẹ̀bẹ iranṣẹ rẹ, ati ti Israeli enia rẹ ti nwọn o ma gbà si ibi yi: iwọ gbọ́ lati ibugbe rẹ wá, ani lati ọrun wá, nigbati iwọ ba gbọ́, ki o si dariji.

22. Bi ọkunrin kan ba ṣẹ̀ si ẹnikeji rẹ̀, ti a si fi ibura le e lati mu u bura, ti ibura na ba si de iwaju pẹpẹ rẹ ni ile yi;

23. Nigbana ni ki o gbọ́ lati ọrun wá, ki o si ṣe, ki o si dajọ awọn iranṣẹ rẹ, ni sisan a fun enia buburu, lati mu ọ̀na rẹ̀ pada sori on tikararẹ̀; ati ni didare fun olododo, lati fifun u gẹgẹ bi ododo rẹ̀.

24. Bi a ba si fọ́ awọn enia rẹ Israeli bajẹ niwaju ọta, nitori ti nwọn ti dẹṣẹ si ọ; ti nwọn ba si pada ti nwọn si jẹwọ orukọ rẹ, ti nwọn si gbadura, ti nwọn si bẹ̀bẹ niwaju rẹ ni ile yi;

25. Nigbana ni ki o gbọ́ lati ọrun wá, ki o si dari ẹ̀ṣẹ Israeli enia rẹ jì, ki o si mu wọn pada wá si ilẹ ti iwọ ti fi fun wọn ati fun awọn baba wọn.

26. Nigbati a ba se ọrun mọ́ ti kò si sí òjo, nitoriti nwọn ti dẹṣẹ si ọ; ṣugbọn bi nwọn ba gbadura si ibi yi, ti nwọn ba jẹwọ orukọ rẹ, ti nwọn ba yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ wọn, nitoriti iwọ pọn wọn loju.

27. Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si dari ẹ̀ṣẹ awọn iranṣẹ rẹ ji, ati ti Israeli enia rẹ, nigbati iwọ ba ti kọ́ wọn li ọ̀na rere na, ninu eyiti nwọn o ma rìn: ki o si rọ òjo si ilẹ rẹ, ti iwọ ti fi fun awọn enia rẹ ni ini.

Ka pipe ipin 2. Kro 6