Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 4:7-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. O si ṣe ọpa-fitila wura mẹwa gẹgẹ bi apẹrẹ wọn, o si fi wọn sinu tempili, marun li apa ọtún, ati marun li apa òsi.

8. O si ṣe tabili mẹwa, o si fi sinu tempili, marun li apa ọtún, ati marun li apa òsi. O si ṣe ọgọrun ọpọ́n wura.

9. O ṣe agbala awọn alufa pẹlu, ati agbala nla, ati ilẹkun fun agbala nla na, o si fi idẹ bo awẹ meji ilẹkun wọn.

10. O si fi agbada na si apa ọtún igun ile ila-õrun, si idojukọ gusu.

11. Huramu si ṣe ikoko, ati ọkọ́ ati ọpọ́n. Huramu si pari iṣẹ na ti o ni iṣe fun Solomoni ọba ni ile Ọlọrun;

12. Ọwọ̀n meji ati ọta, ati ọpọ́n ti o wà li ori ọwọ̀n mejeji na, ati iṣẹ ẹ̀wọn meji lati bo ọta meji ti ọpọ́n na, ti o wà li ori awọn ọwọ̀n na;

13. Ati irinwo pomegranate li ara iṣẹ ẹ̀wọn meji na, ẹsẹ meji pomegranate li ara iṣẹ ẹ̀wọn kan, lati bo ọta meji na ti ọpọ́n ti o wà lori awọn ọwọ̀n na.

14. O si ṣe ijoko, o si ṣe agbada li ori awọn ijoko na.

15. Agbada nla kan, ati malu mejila labẹ rẹ̀.

16. Ati ikoko ati ọkọ́, ati kọkọrọ-ẹran, ati gbogbo ohun-elo ni Huramu-Abi fi idẹ didan ṣe fun Solomoni ọba, fun ile Oluwa.

Ka pipe ipin 2. Kro 4