Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 4:6-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. O ṣe agbada mẹwa pẹlu, o si fi marun si apa ọtún, ati marun si apa òsi, lati wẹ̀ ninu wọn: iru nkan ti nwọn fi nrubọ sisun ni nwọn nwẹ̀ ninu wọn; ṣugbọn agbada na ni fun awọn alufa lati ma wẹ̀.

7. O si ṣe ọpa-fitila wura mẹwa gẹgẹ bi apẹrẹ wọn, o si fi wọn sinu tempili, marun li apa ọtún, ati marun li apa òsi.

8. O si ṣe tabili mẹwa, o si fi sinu tempili, marun li apa ọtún, ati marun li apa òsi. O si ṣe ọgọrun ọpọ́n wura.

9. O ṣe agbala awọn alufa pẹlu, ati agbala nla, ati ilẹkun fun agbala nla na, o si fi idẹ bo awẹ meji ilẹkun wọn.

10. O si fi agbada na si apa ọtún igun ile ila-õrun, si idojukọ gusu.

11. Huramu si ṣe ikoko, ati ọkọ́ ati ọpọ́n. Huramu si pari iṣẹ na ti o ni iṣe fun Solomoni ọba ni ile Ọlọrun;

12. Ọwọ̀n meji ati ọta, ati ọpọ́n ti o wà li ori ọwọ̀n mejeji na, ati iṣẹ ẹ̀wọn meji lati bo ọta meji ti ọpọ́n na, ti o wà li ori awọn ọwọ̀n na;

13. Ati irinwo pomegranate li ara iṣẹ ẹ̀wọn meji na, ẹsẹ meji pomegranate li ara iṣẹ ẹ̀wọn kan, lati bo ọta meji na ti ọpọ́n ti o wà lori awọn ọwọ̀n na.

14. O si ṣe ijoko, o si ṣe agbada li ori awọn ijoko na.

15. Agbada nla kan, ati malu mejila labẹ rẹ̀.

16. Ati ikoko ati ọkọ́, ati kọkọrọ-ẹran, ati gbogbo ohun-elo ni Huramu-Abi fi idẹ didan ṣe fun Solomoni ọba, fun ile Oluwa.

17. Ni pẹtẹlẹ Jordani ni ọba dà wọn, ni ilẹ amọ̀ li agbedemeji Sukkoti ati Seredata.

18. Bayi ni Solomoni ṣe gbogbo ohun-elo wọnyi li ọ̀pọlọpọ: nitori ti a kò le mọ̀ ìwọn idẹ na.

19. Solomoni si ṣe gbogbo ohun-elo ti iṣe ti ile Ọlọrun, pẹpẹ wura pẹlu, ati awọn tabili lori eyi ti akara ifihan wà;

20. Ọpa-fitila pẹlu ati fitila wọn, ki nwọn ki o ma jo gẹgẹ bi aṣẹ niwaju ibi-mimọ́-jùlọ, jẹ wura daradara.

21. Ati itanna, ati fitila ati ẹ̀mu li o fi wura ṣe; gbogbo eyi ni wura daradara;

Ka pipe ipin 2. Kro 4