Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 4:2-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. O si ṣe agbada didà nla, igbọnwọ mẹwa lati eti kan de eti ekeji, o ṣe birikiti, igbọnwọ marun si ni giga rẹ̀; okùn ọgbọ̀n igbọ̀nwọ li o si yi i kakiri:

3. Aworan malu si wà labẹ rẹ̀ yi i kakiri, nwọn si lọ yi agbada nla na kakiri: igbọnwọ mẹwa yi i ka, ọwọ́ meji malu li a dà ni didà wọn kan.

4. O duro lori malu mejila wọnni, mẹta nwò iha ariwa, ati mẹta nwò iwọ-õrun, ati mẹta nwò gusu ati mẹta nwò iha ilà-orun: a si gbé agbada na ka ori wọn, gbogbo iha ẹhin wọn si wà ninu.

5. O si nipọn to ibu atẹlẹwọ, a si fi itanna lili ṣiṣẹ eti rẹ̀ gẹgẹ bi eti ago, o si gbà, o si da ẹgbẹdogun ìwọn bati duro.

6. O ṣe agbada mẹwa pẹlu, o si fi marun si apa ọtún, ati marun si apa òsi, lati wẹ̀ ninu wọn: iru nkan ti nwọn fi nrubọ sisun ni nwọn nwẹ̀ ninu wọn; ṣugbọn agbada na ni fun awọn alufa lati ma wẹ̀.

7. O si ṣe ọpa-fitila wura mẹwa gẹgẹ bi apẹrẹ wọn, o si fi wọn sinu tempili, marun li apa ọtún, ati marun li apa òsi.

8. O si ṣe tabili mẹwa, o si fi sinu tempili, marun li apa ọtún, ati marun li apa òsi. O si ṣe ọgọrun ọpọ́n wura.

9. O ṣe agbala awọn alufa pẹlu, ati agbala nla, ati ilẹkun fun agbala nla na, o si fi idẹ bo awẹ meji ilẹkun wọn.

10. O si fi agbada na si apa ọtún igun ile ila-õrun, si idojukọ gusu.

11. Huramu si ṣe ikoko, ati ọkọ́ ati ọpọ́n. Huramu si pari iṣẹ na ti o ni iṣe fun Solomoni ọba ni ile Ọlọrun;

12. Ọwọ̀n meji ati ọta, ati ọpọ́n ti o wà li ori ọwọ̀n mejeji na, ati iṣẹ ẹ̀wọn meji lati bo ọta meji ti ọpọ́n na, ti o wà li ori awọn ọwọ̀n na;

13. Ati irinwo pomegranate li ara iṣẹ ẹ̀wọn meji na, ẹsẹ meji pomegranate li ara iṣẹ ẹ̀wọn kan, lati bo ọta meji na ti ọpọ́n ti o wà lori awọn ọwọ̀n na.

14. O si ṣe ijoko, o si ṣe agbada li ori awọn ijoko na.

15. Agbada nla kan, ati malu mejila labẹ rẹ̀.

Ka pipe ipin 2. Kro 4