Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 36:20-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Awọn ti o ṣikù lọwọ idà li o kó lọ si Babeli; nibiti nwọn jẹ́ iranṣẹ fun u, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ titi di ijọba awọn ara Persia:

21. Lati mu ọ̀rọ Oluwa ṣẹ lati ẹnu Jeremiah wá, titi ilẹ na yio fi san ọdun isimi rẹ̀; ani ni gbogbo ọjọ idahoro on nṣe isimi titi ãdọrin ọdun yio fi pé.

22. Li ọdun kini Kirusi, ọba Persia, ki ọ̀rọ Oluwa lati ẹnu Jeremiah wá ki o le ṣẹ, Oluwa ru ẹmi Kirusi, ọba Persia, soke, ti o si ṣe ikede ni gbogbo ijọba rẹ̀, o si kọ iwe pẹlu, wipe,

23. Bayi ni Kirusi, ọba Persia, wi pe, Gbogbo ijọba aiye li Oluwa Ọlọrun fi fun mi, o si ti paṣẹ fun mi lati kọ́ ile kan fun on ni Jerusalemu, ti mbẹ ni Juda. Tani ninu nyin ninu gbogbo awọn enia rẹ̀? Oluwa Ọlọrun rẹ̀ ki o pẹlu rẹ̀, ki o si gòke lọ.

Ka pipe ipin 2. Kro 36