Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 36:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA ni awọn enia ilẹ na mu Jehoahasi, ọmọ Josiah, nwọn si fi i jọba ni ipò baba rẹ̀ ni Jerusalemu.

2. Ẹni ọdun mẹtalelogun ni Jehoahasi, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba oṣu mẹta ni Jerusalemu.

3. Ọba Egipti si mu u kuro ni Jerusalemu, o si bù ọgọrun fadakà ati talenti wura kan fun ilẹ na.

4. Ọba Egipti si fi Eliakimu, arakunrin rẹ̀, jọba lori Juda ati Jerusalemu, o si pa orukọ rẹ̀ dà si Jehoiakimu; Neko si mu Jehoahasi, arakunrin rẹ̀, o si mu u lọ si Egipti.

5. Ẹni ọdun mẹdọgbọn ni Jehoiakimu, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mọkanla ni Jerusalemu; o si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀,

6. Nebukadnessari, ọba Babeli, gòke wá, o si dè e ni ẹ̀won, lati mu u lọ si Babeli.

7. Nebukadnessari kó ninu ohun-elo ile Oluwa lọ si Babeli pẹlu, o si fi wọn sinu ãfin rẹ̀ ni Babeli.

8. Ati iyokù iṣe Jehoiakimu ati awọn ohun-irira rẹ̀ ti o ti ṣe, ti a si ri ninu rẹ̀, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Israeli ati Juda: Jehoiakini, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.

9. Ẹni ọdun mejidilogun ni Jehoiakini nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba oṣù mẹta ati ijọ mẹwa ni Jerusalemu: o si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa.

10. Ati li amọdun, Nebukadnessari ranṣẹ, a si mu u wá si Babeli, pẹlu ohun-elo daradara ile Oluwa, o si fi Sedekiah, arakunrin rẹ̀, jọba lori Juda ati Jerusalemu.

Ka pipe ipin 2. Kro 36