Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 33:16-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. O si tun pẹpẹ Oluwa ṣe, o si rú ẹbọ alafia ati ẹbọ ọpẹ lori rẹ̀, o si paṣẹ fun Juda lati ma sìn Oluwa Ọlọrun Israeli.

17. Sibẹ awọn enia nṣe irubọ ni ibi giga wọnni, kiki si Oluwa, Ọlọrun wọn nikan ni.

18. Ati iyokù iṣe Manasse, ati adura rẹ̀ si Ọlọrun rẹ̀, ati ọ̀rọ awọn ariran ti o ba a sọ̀rọ li orukọ Oluwa Ọlọrun Israeli, kiye si i, o wà ninu iwe ọba Israeli.

19. Adura rẹ̀ na pẹlu, bi Ọlọrun ti gbọ́ ẹ̀bẹ rẹ̀, ati gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ati irekọja rẹ̀ ati ibi ti o gbe kọ́ ibi giga wọnni ti o si gbé ere-oriṣa kalẹ, ati awọn ere yiyá, ki a to rẹ̀ ẹ silẹ, kiye si i, a kọ wọn sinu iwe itan Hosai.

20. Manasse si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i si ile on tikalarẹ̀: Amoni, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.

21. Ẹni ọdun mejidilogun ni Amoni, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun meji ni Jerusalemu.

22. O si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa, bi Manasse, baba rẹ̀ ti ṣe, nitori Amoni rubọ si gbogbo awọn ere yiyá, ti Manasse baba rẹ̀ ti ṣe, o si sìn wọn:

23. Kò si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju Oluwa bi Manasse, baba rẹ̀, ti rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ; ṣugbọn Amoni dẹṣẹ pupọpupọ.

Ka pipe ipin 2. Kro 33